Kókó márùn-ún nípa bí ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ yóò ṣe máà ṣiṣẹ́ bó ṣe wà nínú àbá òfin ìdásílẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abadofin kan ti wọn gbe kalẹ nile aṣojuṣofin Naijiria eleyi ti yoo mu iyipada ba ofin ilẹ naa to da lori yiyan awọn kọmiṣana ọlọpaa ti re kọja ipele keji.
Lọjọ Iṣẹgun ni eleyi waye.
Ninu atunṣe yi labẹ ofin Naijiria,wọn yoo fun gomina lagbara lati yan kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ laarin awọn ọlọpaa to wa ni ipinlẹ rẹ.
Eyi wa lara awọn atunṣe si iwe ofin eleyi to n wa bi awọn ipinlẹ naa yoo ṣe ni ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn yatọ si bo ṣe wa tẹlẹ pe labẹ ikapa ijọba apapọ nikan ni awọn ọlọpaa wa.
Ko si ṣẹyin ipenija aabo to kale ka oko ni Naijiria lọwọ yi ti awọn janduku ajinigbe ati awọn alaburu mii ti n fi awọn ọmọ Naijiria da ara to wu wọn.
Tohun ti bi awọn ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n da orisi ọgbọn lati koju awọn ọdaran, ko jọ bii wi pe ipa wọn ka ipenija aabo to wa nilẹ yii.
Ijọba apapọ ati ti ipinlẹ lo dijọ lagbara lori idasilẹ ọlọpa ipinlẹ
Abadofin yi fẹ mu iyipada ba iwe ofin Naijiria ati abala ofin ti tẹlẹ to da lori idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
Orukọ rẹ lede gẹẹsi ni ‘A Bill for an Act to alter the Constitution of the Federal Republic of Nigeria, 1999 to Provide for Establishment of State Police and Related Matters,’
Igbakeji olori ile aṣojuṣofin Benjamin Kalu ati awọn mẹrinla kan lo da laba pe ki wọn gbe abala ofin yi si eleyi ti ijọba apapọ ati ti ipinlẹ le jijọ lagbara lori rẹ.
Ni inu ofin ọdun 1999 bo ṣe wa tẹlẹ, ijọba apapọ nikan ni iwe ofin gbagbara fun lati le ṣe akoso ọrọ ileeṣẹ ọlọpaa.
Asoju Tolani Shagaya to n ṣoju ẹkun idibo iwọ oorun Ilorin, Asa jijọ daba iyipada ofin yi gẹgẹ bo ṣe wa ninu abala Kẹrinla 14(2)(b) to sọrọ nipa aabo ati igbayegbadun awọn ọmọ Naijiria.
Awọn iyipada pataki ti abadofin yi mu wa nipa idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ
Alaye ree lori awọn iyipada ti abadofin yi n gboyanju lati mu ba ilana eto ati iṣakoso ọrọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria
Gbigbe agbara akoso ọlọpaa kuro ni ikapa ijọba apapọ nikan
Koko kan to ṣe pataki ree ninu awọn iyipada ti abadofin yi fẹ mu wa.
Lati igba ti Naijiria ti n tẹle iwe ofin to wa nilẹ yi ni agbara iṣakoso ọlọpaa ti wa ni abẹ aabo ijọba apapọ nikan ninu ilana taa n pe ni ''exclusive list'' aOhun ti eleyi tunmọ si ni pe ijọba ipinlẹ ati ibilẹ ko lagbara lori yiyan eeyan siṣẹ ọlọpaa sisan owo oṣu rẹ tabi iṣakoso ohun elo fun wọn.
Amọ bayii wọn n daba ninu abadofin yi pe ki wọn gbe agbara yi sabẹ ilana ''concurrent list'' ti ijọba apapọ ati ti ipinlẹ yoo jijọ ni agbara lori akoso iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
Idasilẹ ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ kọọkan
Aṣoju Tolani Shagaya ṣalaye wi pe abadofin yi yoo mu iyipada ba ilana to de idasilẹ ajọ ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ipinlẹ Naijiria kọọkan.
Ṣaaju asiko yi, ileeṣẹ kan ṣoso labẹ akoso ijọba apapọ lo n dari iṣakoko gbogbo ohun to niṣe pẹlu didari iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
Awọn ajọ ti ipinlẹ yi naa yoo ni agbara ti wọn ati ojuṣe ti wọn yoo maa ṣe.
Bẹẹ naa ni wọn yoo mu iyipada ba ajọ ileeṣẹ ọlọpaa apapọ Naijiria ti awọn alaga ajọ ti ipinlẹ naa yoo wa lara awọn ọmọ igbimọ rẹ.
Eleyi yoo mu ajọṣepo to murege waye laarin awọn to n dari ileeṣẹ ọlọpaa apapọ ati ti ijọba ipinlẹ kọọkan.
Ipese iranwọ to munadoko fun awọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ
Lara awọn aba mii to wa ninu iyipada ofin yi ni iranwọ owo.
Lati le koju awọn ipenija owo ina, ijọba apapọ yoo y owo sọtọ ni iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ.
Aba naa sọ pe ile aṣofin yoo buwọlu iye owo yi pẹlu ajọṣẹpọ ijọba ki iya owo m ba jẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ lẹyin ti wọn da wọn silẹ tan.
Yiyan kọmiṣana ọlọpaa ni ipinlẹ
Iyansipo Kọmiṣana ọlọpaa ti yoo dari akoso iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ jẹ koko kan pataki ti o maa n jẹyọ ninu ọrọ to niṣe pẹlu idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ.
Idi si ni pe lọpọ igba ni Kọmiṣana kii gba aṣẹ lati ọdọ Gomina ipinlẹ ti wọn ba gbe lọ lati ṣiṣẹ.
Koda awọn Kọmiṣana ọlọpaa mii a maa tẹle aṣẹ lati ọwọ ijọba apapọ ti wọn fun ọga agba ọlọpaa lati yaju si Gomina ipinlẹ ni igba mii.
Amọ aba yi fẹ ko ṣe pe Gomina ni yoo yan Kọmiṣana ọlọpaa ni ipinlẹ rẹ pẹlu ajọṣepọ pẹlu ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ati ile aṣofin ipinlẹ naa.
Yiyọ Kọmiṣana nipo nkọ?
Gomina ipinlẹ tabi awọn mii to baa n paṣẹ lorukọ rẹ le paṣẹ to lẹtọ fun Kọmiṣana to si gbọdọ tẹle.
Ti o ba wa ri wi pe aṣẹ yi tapa si ofin, Kọmiṣana ọlọpaa le kọ lati tẹlẹ amọ yoo fi ọrọ naa to ajọ ileeṣẹ ọlọpaa leti fun igbesẹ to ba yẹ ko tẹle.
Amọ nibi ti Kọmiṣana ba ti ṣe aṣemaṣe ti wọn si ribi fidi eleyi mulẹ, Gomina laṣẹlati yọ nipo lopin igba ti ida mẹta ninu awọn aṣofin ile aṣofin ipinlẹ.















