Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ alàkọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ wà ní bèbè ikú, lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá yìnbọn mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbofinro ti mu ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹtala kan fun ẹsun pe o yinbọn mọ ọga ile ẹkọ rẹ, to si pa a lara.
Ọmọdekunrin naa ti wọn ko darukọ rẹ, ni wọn fi ẹsun igbiyanju lati paniyan kan.
Ẹni ọdun mọkanlelaadọta to yinbọn mọ, wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nileewosan.
Iyalẹnu nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun ọpọlọpọ eeyan ni orile-ede South Africa, paapaa bi ibẹru ṣe wa lori bi iwa jagidijagan ṣe n gbilẹ ni awọn ile ẹkọ.
Iroyin sọ pe ibọn baba rẹ ni ọmọ naa yin mọ ọga ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to wa niluu Germiston, ti ko fi bẹẹ jina si Johannesburg.
Awọn agbofinro ti mu baba rẹ naa, fun ẹsun pe ko mojuto ibọn rẹ daadaa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Col Dimakatso Nevhuhulwi, sọ fun BBC pe baba naa yoo f'ojú ba ile ẹjọ.
Lasiko abẹwo to ṣe si ile ẹkọ naa lọjọ Aje, minisita fun eto ẹkọ ni ẹkùn Gauteng, Matome Chiloane, fi ẹsun kan pe ọmọdekunrin naa ni akọsilẹ orukọ olukọ mẹta to fẹ ẹ pa, nitori pe wọn n yọ ọ lẹnu nile ẹkọ
"Nigba ti a fi ọrọ wa awọn ọrẹ rẹ lẹnu wo, wọn sọ pe ọjọ ti pẹ to ti gbero igbesẹ naa.
" Iwadii tun fihan pe wọn ma n ṣe ipade lori ayelujara ibaraẹnisọrọ WhatsApp, nibi ti wọn ti jọ gbero iṣẹlẹ buruku yii."
Ijiya wo lo wa fun ẹsun yii?
Labẹ ofin fun igbẹjọ awọn ọmọde ni orile-ede South Africa, igbagbọ ni pe ọmọ ọdun mejila tabi mẹtala, ko ni agbara lati hu iwa ọdaran, ayafi ti ijọba ba ri ẹri fi gbe ẹsun lẹsẹ.
Lori ọrọ ọmọde yii, ile ẹjọ majisireti kan ti paṣẹ pe ki iwadii waye, lati mọ boya ọmọ naa dá pé ninu ero, iwa, ẹkọ ile, ati ibaṣepọ laarin awujọ.
Eyi waye lẹyin ti ajọ to n gbẹjọ ro fun ijọba kọwe beere fun.
Lẹyin iwadii naa ni adajọ majisireti yoo sọ boya wọn le gbọ ẹjọ rẹ bii ti agbalagba.
Eto aabo ni awọn ile ẹkọ jẹ ipenija nla ni Gauteng.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn gun akẹkọọ kan pa, ti òmíràn tun fi ara gba ọgbẹ nile ẹkọ girama kan ni Gusu Johannesburg.















