"Mo ṣẹ́ oyún oge torí ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ṣọ́ọ̀ṣì pa mí tì, ilé ọmọ mi bàjẹ́, dókítà ní n kò le bímọ mọ́"

Àkọlé fídíò, Abortion Law: Obìnrin tí ilé ọmọ rẹ̀ bàjẹ́ rọ ìjọba láti ṣe òfin tó fààyè gba oyún ṣíṣẹ́
"Mo ṣẹ́ oyún oge torí ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ṣọ́ọ̀ṣì pa mí tì, ilé ọmọ mi bàjẹ́, dókítà ní n kò le bímọ mọ́"
Abike Ajere

Yoruba ni abamọ lo n gbẹyin ọrọ, ẹni a wi fun, ọba jẹ ko gbọ.

Ọpọ ọmọge lo ti se asise nini oyun abaadi, oyun apete tabi oyun oge, ti wọn ko si ri ẹni gba a lọwọ wọn.

Koda, aye awọn ọmọge miran ti bajẹ tori asise nini ibalopọ lai duro de akoko to yẹ, ti wọn ko si le tẹsiwaju pẹlu ẹkọ wọn mọ nile iwe.

Amọ eyi to buru julọ ninu ipa ti nini oyun oge maa n ni iku oju awọn ọmọge lasiko ti wọn ba fẹ sẹ oyun naa lọna to lodi sofin.

Eyi ti ko ba si ku iku ojiji ninu wọn ni ile ọmọ wọn maa n bajẹ, ti wọn ko ni ri ọmọ bi mọ lasiko ti wọn dele ọkọ.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu Abike Ajere ( Kii se orukọ rẹ gangan ree) to ba BBC Yoruba sọrọ lori ọpọ ipenija to ri lasiko to ni oyun apete ati idi to fi sẹ oju naa.

“Ẹbi, ara, ọrẹ ati ijọ Ọlọrun to pa mi ti lasiko ti mo loyun, lo jẹ n lọ sẹyun naa”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Abike Ajere ni oun ati ọrẹkunrin oun ni awọn sere ifẹ lọdun 2013, ti oyun airotẹlẹ si de.

O ni bi asiri oyun naa se tu sita, ni awọn obi oun, to fi mọ awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati ijọ Ọlọrun ti awọn n lọ pa oun ti, ti wọn ko si fẹ ri imi oun lori aatan.

"Eyi lo mu ki n lọ sile iwosan lati lọ sẹyun naa amọ tori pe ijọba ko fi aaye gba oyun sisẹ, awọn dokita ko sẹ oyun naa fun mi.

Mo wa gba ọdọ Nọọsi kan lọ ni adugbo wa, o sẹ oyun yii amọ se ni ẹjẹ n da loju ara mi lai dawọ duro, ti ẹmi mi si fẹrẹ ba isẹlẹ naa lọ"

"Dokita ni n ko le loyun mọ debi pe maa bimọ laye tori ile ọmọ mi ti bajẹ"

Abike Ajere fikun pe wọn gbe oun lọ sile iwosan lati le jẹ ki ẹjẹ naa da, ki wọn si du ẹmi oun.

Amọ o ni lẹyin ti oun ri iwosan to peye, ara oun da amọ ikede dokita nipa isẹlẹ naa mu ibanujẹ ayeraye ba oun.

"Lẹyin ti ara mi ya tan, ni Dokita sọ fun mi pe ile ọmọ mi ti bajẹ, o ni n ko le loyun mọ laelae, debi pe maa bimọ laye.

O ni ayederu Nọọsi ti mo tọ lọ ti se ijamba nla si ile ọmọ mi.

Inu mi bajẹ, ti ibanujẹ si dori mi kodo, bẹẹ ni itiju ati ibẹru awọn ẹbi ati ọrẹ pẹlu ijọ Ọlọrun ti mo n lọ, lo sun mi de ipo yii."

Mo pada se igbeyawo, bimọ meji lẹyin ti awọn dokita ti kede pe n ko le lọmọ laye mọ"

Amọ awọn agba ni bo ti wu Oluwa lo n se ọla, to si maa n pada sọ ibi di rere.

Abike Ajere tẹsiwaju pe oun se igbeyawo lọdun 2019 lẹyin isẹlẹ naa, ti oun si finu soyun lẹyin o rẹyin.

O ni oun bimọ meji fun ọkọ oun lẹyin tawọn dokita ti kede saaju pe ile ọmọ oun ti bajẹ, ti oun ko si le se abiyamọ m laye.

"Inu mi dun pe mo pada finu soyun, mo si fi ẹyin mi gbe ọmọ pọn, ti ko si ri fun mi ggẹ bi awọn dokita ti kede rẹ."

"Mo n rọ ijọba lati kede ofin ti yoo fi aaye gba oyun sisẹ nile iwosan ka le dena iku airọjọ tabi airọmọbi laarin awọn ọmọge"

Abike Ajere wa salaye nipa awọn ewu to rọ mọ nini oyun oge laarin awọn ọdọbinrin eyi to n mu ọpọ wahala dani.

O ni ko tọ rara fawọn obi lati maa ta awọn ọmọbinrin wọn to ba loyun apete nu nitori eyi le fa ọpọ idaamu lọjọ iwaju.

"Mo n rọ awọn obi lati fa awọn ọmọ wọn to ba loyun airotẹlẹ mọra, ko dara ki wọn maa ta wọn nu nitori ewu to wa nidi iwa yii.

Bakan naa ni mo n rọ ijọba lati kede ofin ti yoo faaye gba oyun sisẹ lọna to bofin mu, paapaa lawọn ile iwosan wa gbogbo.

Eyi ni yoo dẹkun tabi mu adinkun ba awọn ọmọge to n ku lojiji ni ọgọọrọ nitori oyun sisẹ tabi ki wọn ma lee bimọ mọ lọjọ iwaju."