Kìnìún fa òṣìṣẹ́ fáṣítì OAU ya lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tó ti ń fún-un ní oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, OAU
Osisẹ ilẹ ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo niluu Ile Ife, Olabode Olawuyi, ti padanu ẹmi rẹ sọwọ kininu to ti n sin fun ọdun mẹsan an.
Atẹjade ti agbẹnusọ ilẹ ẹkọ fasiti naa, Abiodun Olarewaju fi lede fun awọn akọroyin, Olawuyi lo jẹ onimọ nipa ẹranko, to si ti n ba ile ẹkọ naa sisẹ fun ọpọlọpọ ọdun ni ẹka ile ẹkọ to n mojuto awọn ẹranko ninu igbo, ‘Zoo’.
Olarewaju ni kininu, to jẹ ẹni ọdun mẹsan an, kọlu Olawuyi lasiko to n fun un ni ounjẹ ni gbagede ẹranko to wa ninu ile ẹkọ Fasiti Obafemi Awolowo.
Gẹgẹ bi Olarewaju ṣe salaye, gbogbo osisẹ yooku to wa ni ibi ti isẹlẹ naa ti waye saa gbogbo akitiyan ati agbara wọn lati dola ẹmi Olawuyi sugbọn ẹranko kininu naa ti gba ẹmi lẹnu ọga wọn.
“Kete ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni a fi to Ọga agba fasiti, Ọjọgbọn Adebayo Simeon leti, to si ni lati kuro nibi ipade to n dari lati lọ wo nhun to waye .
“Ọga agba Fasiti pasẹ pe ki gbogbo ẹka ilera to wa ni ile ẹkọ saa akitiyan wọn lati dola ẹmi Olawuyi sugbọn pabo lo jasi.
“Isẹlẹ yii lo fa ti a fi gba ẹmi eranko kininu naa.
“Olawuyi ti n tọju awọn kininu yii lati ọdun méan an sẹyin sugbọn o bani lọkan jẹ pe kininu naa ṣekupa ẹni to ti n fun wọn ni ounjẹ jẹ.
“Awọn alasẹ fasiti ti ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi oloogbe, to si rọ wọn lati gba pe a mu wa Ọlọrun ni.”
Olarewaju wa fikun pe Ọga Fasiti ti pasẹ pe ki iwadii lori ohun to sokunfa iku Olabode Olawuyi bẹrẹ ni kiakia .
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















