Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní America wọ́gilé oyún ṣíṣẹ́ fún àwọn obìnrin

Awọn obinrin to n ṣe iwọde nitori oyun ṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

ile ẹjọ to ga julọ pa ofin to faaaye gba wọn run.

Lati aadọta ọdun sẹyin ni ofin naa ti wa, eyi to fun awọn obinrin lorilẹ-ede naa ni anfaani lati sẹyun.

Idajọ naa waye lẹyin ọsẹ diẹ ti iwe kan lu jade si gbangba, eyi to ṣafihan pe wọn n gbeero lati yi idajọ ofin naa pada.

Pẹlu idajọ yii, gbogbo ipinlẹ to wa ni America, ti ni agbara lati fi ofin de oyun ṣiṣẹ. Nitori eyi, ilaji awọn ipinlẹ naa ni ireti wa pe yoo gbe ofin ati ilana tuntun jade nipa rẹ tabi ki wọn fi ofin de e.

Mẹtala ninu wọn ti buwọlu ofin ti yoo pa oyun ṣiṣẹ run patapata.

Ajọ kan to n risi eto ibimọ, Planned Parenthood, sọ pe o to miliọnu mẹrindinlogoji obinrin ti ko ni lanfaani si oyun ṣiṣẹ mọ.

Ile ẹjọ giga naa ṣagbeyẹwo ẹjọ kan ti ajọ Dobbs v Jackson Women’s Health Organization, pe lori bi ijọba ipinlẹ Mississippi ṣe fofin de ṣiṣẹ oyun to ba ti le ni ọsẹ mẹẹdogun.

Ipinlẹ naa si ni ẹjọ gbè. Ile ẹjọ sọ pe ofin ko fun ẹnikẹni ni anfaani lati ṣẹ oyun, ati pe aṣẹ lati ṣe ilana fun oyun ṣiṣẹ gbọdọ pada si ọwọ awọn araalu ati awọn aṣoju wọn ti wọn dibo yan sile aṣofin.

Ṣaaju ni awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu Democrat, ni ipinlẹ bi California, New Mexico ati Michigan, kede pe awọn fẹ fi ẹtọ si oyun ṣiṣẹ sinu ofin wọn, ti ile ẹjọ ba fi wọgile ofin to faaye gba a.

Ileeṣẹ iroyin Reuters sọ pe igbakeji aarẹ, Kamala Haris, ṣe ipade pẹlu awọn agbẹjọro agba fun awọn ipinlẹ ti Democrats n dari, lọjọbọ, lori ọna ti wọn le gba ṣe atilẹytin fun oyun ṣiṣẹ.

Ọdun 1973 ni ofin Roe v Wade, ti wa, eyi to fun awọn obinrin ni ẹtọ lati ṣẹ oyun laarin oṣu mẹta akọkọ.

Bakan naa lo tun ni ilana fun oyun to ba ti ju oṣu mẹta lọ, to si fi ofin de eyi to ba ti wọn oṣu meje soke.