“Mo ṣetán láti fi ọ̀kan nínú kíndìnrín mi sílẹ̀ fún ọmọ Ekweremadu”

Wọ́n ti fi hàn mí lójú oorun láti ran ọmọ Ekeremadu lọ́wọ́ lórí àìsàn kíndìnrín rẹ̀ - Martha Uche

Ike Ekweremadu ati Martha Uche

Oríṣun àwòrán, Martha Uche

Arabinrin kan Martha Uche ti kede fun araye pe oun setan lati fi ọkan ninu kindinrin oun silẹ fun Sonia, ọmọ Ike Ekweremadu to n saisan nilu ọba.

Fidio kan to gba ori ayelujara kan lo sisọ loju ikede naa ati idi ti arabinrin naa se fẹ se iranwọ ọhun.

Martha salaye pe oju oorun ni oun ti ri pe oun gbọdọ seranwọ fun ọmọbinrin to n saisan naa.

“Mo gbọdọ ran obinrin naa lọwọ nitori pe o n ku lọ. Wọn ti fi han mi loju oorun pe mo gbọdọ ran obinrin naa lọwọ.

Ọjọ pẹ ti mo ti ri, wọn ti fi han mi loju oorun, mo si gbọdọ se kankan nipa igbesẹ mi ọhun.

N ko beere ohunkohun lasiko yii, mo kan setan lati doola ẹmi obinrin naa ni, ohun to kọkọ se pataki si mi ree.

Bẹẹ ba gbagbe, ileesẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi lo mu igbakeji aarẹ ile asofin agba nigba kan ri, Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ, Beatrice, ti wn si gbe wọn lọ sile ẹjọ.

Ẹ̀sun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn mu mọde wa silu ba lati wa yọ awọn ẹya ara rẹ

Iléẹjọ́ fi Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀ sí àtìmọ́lé dí oṣù tó ń bọ̀
Ekweremadu ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Ike Ekweremadu/ facebook

Igbakeji aarẹ ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ Beatrice Nwanneka Ekweremadu yoo ṣi wa ni atimọle awọn ọ̀lọpaa ilẹ Gẹẹsi titi di ọjọ keje oṣu keje ọdun yii.

Awọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi mu awọn mejeeji lọ siwaju ile ẹjọ Majisireeti kan lọjọbọ lori ẹsun pe wọn n fi ẹya ara eniyan ṣowo.

Awọn mejeeji yii fara han niwaju ile ẹjọ majisireeti Uxbridge fun igba akọkọ igbẹjọ wọn ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa.

Olupẹjọ, Damla Ayas ṣalaye fun ile ẹjọ naa pe lori ẹsun ti wọn wọn fi kan Ekweremadu ati aya rẹ naa, yoo nilo ki amofin agba o buwọlu

“ọjọ mẹrinla nileeṣẹ ọbabinrin si gba wọn laaye lati ri aṣẹ naa gba”

Awijare olupẹjọ naa lo mu ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju fun ọjọ mẹrinla lẹyin ti wọn ṣe e lalaye fun un pe tọkọtiyawo lawọ olujẹjọ mejeeji.

Pupọ ẹsun ti wọn ṣẹ si naa lo waye lori ilẹ Gẹẹsi, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to ileẹjọ naa leti.

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelogun ni wọn mu awọn eekan ọmọ Naijiria mejeeji naa.

Kini ẹsun ti wọn fi kan Ekweremadu ati aya rẹ?

Ekweremadu ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Ike Ekweremadu/ facebook

Ileeṣẹ Ọlọpaa Met ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si BBC pe,

“ẹsun igbimọpọ ṣeto irinajo silẹ okeere fun eeyan kan pẹlu erongba lati fi ẹya ara onitọhun ṣowo” ni wọn kan awọn mejeeji

Atẹjade naa ni awọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iṣẹ nigba ti wọn ta wọn lolobo nipa igbesẹ kan to tako ofin owo ẹru igbalode ti osu karun un ọdun 2022.

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ni awọn ti gba ọmọ naa fun idaabobo, ti awọn si n ṣiṣẹ pọ pẹlawọn ajọ aṣeranwọ kan fun itọju rẹ

Igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ̀, Ike Ekweremadu àti aya rẹ̀ wọ gbaga nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí ẹ̀sùn òwò ẹ̀ya ara ènìyàn 

Ike Ekweremadu ni ile aṣofin agba

Oríṣun àwòrán, Ike Ekweremadu / facebook

Àkọlé àwòrán, Ekweremadu ti fi igbakan ri jẹ igbakeji aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria.

Ijọba UK ni Ekweremadu ati iyawo rẹ gbimo po lati gbe ọmọ kan wọ orile-ede naa lati ko àwọn ẹyẹ ara ọmọ naa.

Ekweremadu ẹni ọgọ́ta ọdun pẹlu ẹni marundilogota ni ọwọ tẹ wọn lẹyin iwadi ti Metropolitan Police Specialist team ṣe lati ṣe afihan pe wọn lọwọ ninu iwa ọdaran naa. Ninu atesita kan ti ileeṣẹ ọlọpaa Met fi ransẹ si ile ise BBC News Yoruba Wọn ní

"Beatrice Nwanneka Ekweremadu, ẹni ọdun marundilogota ni iwadi fihan pe o ledi apupo pẹlu awọn kan lati mu ọmọ kan wa lati ko ifun."

"Ike Ekweremadu, ẹni ogota ọdun ni iwadi fihan pe o ledi apupo pẹlu awọn kan lati mu ọmọ kan wa lati ko ifun."