Èmi olùdíjé sípò gómìnà, wọ́n tún ń pè mí kí n wá ra ìbò - Àṣírí tú lẹ́nu olùdíje méjì míì

"Kí n tó kúrò nílé ni àwọn ọmọ ìlú mi ti ń bèrè lọ́wọ́ mi pé ṣe mo ṣetán láti ra ìbò".
Lẹyin ti oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress jawe olubori gẹgẹ bii gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Ekiti ti ba araalu sọrọ lati tan imọlẹ si gbogbo ohun to ṣẹlẹ lasiko idibo naa, awọn oludije ẹgbẹ mii ti sọ ọrọ to yatọ sita.
Oludije ẹgbẹ oṣelu awọn ọdọ to si jẹ oludije to kere julọ, Adeyinka Alli ti ẹgbẹ APP ṣalaye ohun ti oju rẹ ri paapaa bi wọn ṣe wa n polowo pe ki oun naa wa ra ibo ko ma ṣe dibo fun ara rẹ, ko lọ dibo fun oludije miran.
Awọn to n pi owo, wọn o le muu mọra mọ, wọn yaa n ṣeto "a n ra ibo" wọn lọ loju mi"
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba pe "ki n to kuro ni ilu mi funra mi ni wọn ti n wa beere lọwọ mi pe ṣe mo maa ra ibo".
O ni ko to di igba ibo, ariwo pe o ti su wa ni awọn araalu nke amọ wọn pada ra ibo wọn naa ni.
"Igba ti mo debẹ, wọn ni ki n wa dibo niwaju, mo ni rara ki awọn to ṣaaju mi de kọkọ dibo mo dẹ to sori ila, wọn o le muu mọra mọ, wọn yaa n ṣeto "a n ra ibo wọn lọ loju mi".
O ni ṣe lawọn ọmọ ilu oun gangan naa tun n bi oun pe ṣe ohun ṣetan lati ra ibo.
Oludije si ipo gomina yii kan naa ninu ẹgbẹ oṣelu ADC to si jẹ oludije obinrin kan ṣoṣo, Kemi Elebute-Halle tu aṣiri iye owo ti awọn ẹgbẹ oṣelu to ku n pin.
"Ẹgbẹ oṣelu wa nikan ni ko ra ibo, a ni ibo 5579, lai ná naira kan".
Arabinrin Elebute-Halle ni awọn ṣẹṣẹ tun bẹrẹ ni awọn o si ni kaarẹ, o ni awọn yoo wọ ẹjọ naa debi pe lu aridaju atawọn ẹri to wa, awọn yoo gbee le awọn ọmọ
Naijiria lọwọ ti yoo si han boya awọn aṣofin naa lo n ru ofin ati pe boya Naijiria ni awọn adajọ olootọ abi bẹẹ kọ.

















