Wo kókó ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Abiodun Oyebanji, olùdíje APC tó mókè nínú ìbò gómìnà Ekiti

Oríṣun àwòrán, @biodunaoyebanji
Ninu esi idibo gomina to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Satide, ọjọ Kejidinlogun osu Kẹfa ọdun 2022, Abiodun Abayomi Oyebanji tẹgbẹ oselu APC lo moke ninu eto idibo naa.
Apapọ ibo to ni eyi to pọ pupọ lo se fi awọn oludije ẹgbẹ oselu SDP, Segun Oni ati ti PDP Kolawole janlẹ ninu eto idibo naa.
O si fi foju han gbangba pe Oyebamiji ni gomina tuntun ti yoo gba ipo lọwọ dokita Kayode Fayemi.
Inu ẹ́gbẹ oselu PDP si ni awọn mejeeji ti wa.
Wo koko ohun ti o ko mọ nipa Abiodun Oyebamiji:
Ọjọ Kọkanlelogun osu Kejila ọdun 1967 ni wọn bi Abiodun Oyebamiji, o si pe ẹni ọdun marundinlọgọta lọdun yii.
Ẹni to gbegba oroke ninu ibo gomina ipinlẹ Ekiti ko sẹsẹ bẹrẹ oselu nitori o ti di ipo akọwe ijọba ipinlẹ naa mu saaju.
Ọmọ bibi ilu Ikogosi nipinlẹ Ekiti ni Oyebamiji, to si lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ tijọ onitẹbọmi to wa nilu naa, Awo Community High school, ko to wa bọ si ile ẹkọ girama C.A.C Grammar school nilu Efon-Alaaye lọdun1979.
Bakan naa lo lọ sile ẹkọ girama fun imọ sayẹnsi to jẹ tijọba ipinlẹ Ondo ijọun ati ile ẹkọ District Commercial Secondary School nilu Aramoko-Ekiti laarin ọdun 1983 si 1985.
Lẹyin ile ẹkọ girama lo tẹsiwaju lọ sile ẹkọ fasiti ijọba ipinlẹ Ondo, Ondo State University to di fasiti Ekiti State University, Ado-Ekiti bayii ldun1989.

Oríṣun àwòrán, @biodunoyebanji
Ẹkọ nipa eto oselu si lo lọ kọ nibẹ ninu eyi to ti gba oye imọ ijinlẹ akọkọ.
Biodun Oyebanji tun gba oye kun oye ninu imọ ẹkọ nipa oselu yii lati fasiti Ibadan.
Biodun Oyebanji sisẹ bii alakoso nile ifowopamọ Omega, to ti kogba wọle amọ to parada di Heritage Bank bayii titi di ọdun 1999.
Lọwọ lọwọ bayii, Biodun Oyebanji ni ọga agba ileese ọgbin Con Dois Farms LTD to n dokowo ninu isẹ agbẹ.
Lagbo oselu, Biodun Abayomi Oyebanji sisẹ bii amugbalẹgbẹ fun ọrọ ile asofin fun gomina ipinlẹ Ekiti laarin ọdun 1999 si 2000.

Oríṣun àwòrán, @biodunoyebanji
Oun naa si tun ni amugbalẹgbẹ si gomina lori ọrọ asofin naa laarin ọdun 2000 si 2001.
Lẹyin naa ni Oyebanji wa di olori osisẹ ni ọọfisi gomina laarin ọdun 2001 si 2003.
Oyebanji tun jẹ Kọmisana fọrọ ijọba kan si ekeji nipinlẹ Ekiti, ko to wa di akọwe ijọba ipinlẹ naa fun gomina Kayode Fayemi.
Ipo yii si lo di mu titi ko to wa pinnu lati dije fun ipo gomina eyi to jawe olubori ninu rẹ bayii.
Biodun Abayomi Oyebanji ifẹ iyawo, Ọjọgbọn arabinrin Oyebanji to n sisẹ́ lọgba fasiti Ibadan, to tun jẹ ọmọ ọbabinrin nilu Ado Ekiti.















