Ènìyàn kan kú, àwọn méje farapa níbi Ìjàmbá ọkọ̀ l’Ekoo

Ìbúdo ìjàmbá ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn kan, tí àwọn méje mìíràn sì farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní agbègbè Alapere, ìpínlẹ̀ Eko ní ìdájí ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kéfà ọdún 2022.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nín;u àtẹ̀jáde kan sọ wí pé àwọn méje ni àwọn dóòlà níní ìjàmbá náà tí àwọn sì rí òkú ẹnìkan yọ.

Ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyitolu ní ọkọ̀ J5 tó kó èrò àti àlùbọ́sà ló lọ kọlu ọkọ̀ ńlá tírélà tó kó igi níbi tó ti ń jáde kúrò nínú ọgbà iléeṣẹ́ kan.

Oke-Osanyitolu ní àwọn tó farapa nínú ìjàmbá náà ni ẹ̀ka tó ń mójútó ìwòsàn àjọ àwọn sáré dálóhùn kí wọ́n tó kó wọn lọ sí ilé ìwòsàn jẹ́nẹ́rà tó wà ní Gbagada.

Ó ní óṣeni láàánú pé ọkùnrin kan tó wà nínú ọkọ̀ J5 tó há sábẹ́ tírélà náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn ti gbé òkú ọkùnrin náà fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fún ètò ìsìnkú tó yẹ.

Ó ní àwọn ti wọ́ àwọn ọkọ̀ ńlá méjéèjì kúrò lọ́nà tí àwọn sì ti fa ọkọ̀ J5 lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.