Ọwọ́ Ọlọ́pàá tè àwọn tó ń ṣe òhun ìjà lọ́nà àìtọ́ àti ọmọ ẹgbẹ òkùnkùn ní Delta

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileese olopaa ipinlẹ Delta ti ṣe afihan arakunrin kan ẹni ogorin ọdun, Omoraka James ti o ṣe ohun ija lọna aitọ fun awọn ọdaran pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ipinlẹ naa .
Ninu atẹjade kan ti agbẹnuso ileese olopaa, DSP Edafe Bright fi si ita fun awọn akoroyin lo ti sọrọ.
Komisn.na fun ileese olopaa ni ipinlẹ naa, CP Ari Muhammed Ali ni ọwọ tẹ arakunrin naa lẹyin ti iroyin tẹ awọn olopaa leti pẹ Omoraka James wa lara awọn to n ṣe ohun ija lona aitọ fun ọpọlọpọ awọn ajinigbe lati fi ṣe ijamba fun awọn ara ipinlẹ naa.
O ni ọwọ tun tẹ awọn afurasi ọdaran miiran lẹyin ti olopaa da wọn duro lopopona morosẹ Sapele si Benin pẹlu oko ayọkẹlẹ bọ si Toyota Hiace.
Nibẹ ni wọn si ka ibon ibilẹ ẹlẹnumeji mefa ti wọn fi agborun kan ti o jẹ ti Arabinrin kan ti oruko rẹ jẹ Victoria Itila.
Bawo ni ọlọpaa se mu ọmọ ẹgbẹ okunkun?
Bakan naa ni ọwọ olopaa tun tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nibi ayẹyẹ igbaniwọlẹ ti wọn ṣe fun swọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ni ile itura Big Apple Hotel ni agbegbe Ogwashi-Uku.
Ọkanlẹlaadọta ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ọwọ olopaa tẹ pẹlu ibon ibilẹ meji ati ota ibon, ti wọn ti fi wọn ransẹ si ileese olopaa ti o ṣe iwadi lori awọm ọmọ ẹgbẹ okunkun(SACU)
Kọmisona naa wa ro awọn obi ati alagbatọ lati ṣe amujoto to pe yẹ lori awọn ọmọ wọn lati ya go fun iwa ọdaran nitori pe ileese olopaa ipinlẹ Delta koni fi aye gba iwa ọdaran tabi iwa ti o ba jẹ mọ ẹgbẹ okunkun ni ipinlẹ naa.












