Láàrín wákàtí 24, ẹ wọ́gilé ojú òpó tó ṣàfihàn ìbálòpọ̀ – Ìjọba pàṣẹ fún Twitter, Facebook…
Social Media Code of Conduct: Ìjọba pàṣẹ fún Twitter, Facebook láti wọ́gilé ojú òpó tó ṣàfihàn ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọba Naijiria ti paṣẹ ki gbogbo oju opo ikansiraẹni bii Twitter, Facebook, Instagram, Whatsapp ati tiktok lati yọ gbogbo oju opo ti wọn ba ti n fi ohunkohun to niiṣe pẹlu ibalopo si oju opo wọn kuro.
Ijọba fi lede ninu iwe ofin tuntun ti wọn pe ni (Code of Practice for Interactive Computer Service Platforms/Internet Intermediaries /online platforms) labẹ ile iṣẹ ijọba .
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, wọn ko gbọdọ fi ihoho sita, tabi aworan ifibanilopọ lati dukoko mọ eniyan.
Bakan naa ni wọn paṣẹ ki awọn oju opo naa ko gbogbo iru nkan bẹẹ kuro ni oju opo wọn.
Won fikun un pe oju opo to ba ti ni ju ọmọ Naijiria 100,000 loju opo wọn lati wa ṣi ọfisi si Naijiria
Ajọ NITDA pelu ileeṣẹ to n risi ọrọ ibanisọrọ, NBC to fi mọ Twitter, Facebook, WhatsApp, Instagram, Google, ati Tik Tok ni wọn jọ gbe kalẹ.








