Iṣẹ́ yóò wà lọ́pọ̀ yanturu l’Ekiti tí mo bá di gómìnà - Adeyinka Ali, olùdíje ẹgbẹ́ APP
Adeyinka Ali: Mo máa pèsè iṣẹ́ yanturu l’Ekiti tí mo bá di gómìnà
Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APP nipinlẹ Ekiti, Adeyinka Ali, ti sọ pe oun yoo pese iṣẹ yanturu fun awọn eeyan ipinlẹ ọhun i wọn ba le dibo gbe ou wọle.
Ali lo sọ bẹẹ ninu itakurọsọ kan pẹlu BBC Yoruba.
O ni bi eto ọrọ aje ipinlẹ Ekiti ṣe ri lọwọ yii ko tẹ oun lọrun, oun si ti ṣetan lati tan iṣoro naa gẹgẹ bii gomina.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, pẹlu gbogbo ohun ti ipinlẹ Ekiti ni ati bi awọn ọmọ ipinlẹ naa ṣe kawe to, ko yẹ ki wọn wa ni irufẹ ipo ti wọn wa bayii.
O ni “Niṣe lo yẹ ki a maa figa-gbaga pẹlu awọn ipinlẹ bii Eko, a le ma ni epo o, amọ awọn ohun ti a ni to wa.”

Nipa eto to ni fu ipinlẹ naa to be di gomina, o ni n fẹ ki ipinlẹ naa dabi orilẹ-ede to da funra rẹ.
Ali tun sọ pe oun ti ṣeto ti aye fi maa rọ awọ ara Ekiti lọrun nipa ipese iṣẹ yatọ si ijọba.
O ni “Ti wọ ba sọ pe ko si iṣẹ l’Ekiti, ko si nnkan to n jẹ bẹẹ... iṣẹ maa wa lọpọ yanturu l’Ekiti.”
Bakan naa lo mẹnu ba bi ijọba ou yoo ṣe lo imọ igbalode lati gbena woju eto abo to mẹhẹ ni ipinlẹ ọhun.













