Lẹ́yìn tí Mbaka tí ilé jọ́sìn pà, awọn ọmọ ìjọ fẹhonuhan lórí àṣẹ Bisọọbu Onaga

aworan awọn ọmọ ijọ Adoration Ministry

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbajugbaja adari ẹka ile ijọsin Aguda, Fada Ejike Mbaka ti tẹle asẹ ati ipinnu awọn adari ijọ aguda, ti o si ti ile jọsin rẹ pa lẹyin ti Bisọọbu Calistus Onaga ti ipinlẹ Enugu ni kii awọn olujọsin ijọ aguda lati dẹkun lilọ ile jọsin Adoration Ministry.

Asẹ naa ni ko dun mọ ọpọ olujọsin Adoration Ministry ninu ti wọn si tu sita lati fẹhonuhan wọn lori iṣẹlẹ naa

Bisọọbu Onaga lo pase awọn fun olujọsin latari ọrọ kan ti gbajugbaja adari ẹka ile ijọsin Aguda naa sọ si Peter Obi, oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party pe ko le e di aarẹ orilẹede Naijiria.

Mbaka ninu atesita sọ fi sita fun awọn akoroyin ni pe ijọsin ko ni waye mọ ni ile jọsin naa.

“Latari asẹ ati ipinnu awọn adari ile jọsin Aguda, ko ni si isin mọ ni ẹka ile jọsin, Adoration Ministry.”

“Ẹma tubo ma gbadura fun Mbaka, oluwa yo wa pẹlu yin.”

aworan fada mbaka

Oríṣun àwòrán, screen shot

aworan bi awọn olujọsin se fẹhonuuhan

Oríṣun àwòrán, screenshot

"Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sì ilé jọ́sìn Mbaka " Àwọn adarì ìjọ sọ fún àwọn olùjọ́sìn

Adari ijọ aguda ni ipinlẹ Enugu, Bisọọbu Calistus Onaga ti pa a lasẹ fun awọn olujọsin ijọ aguda lati dẹkun lilọ si ile ijọsin, Fr. Ejike Mbaka Adoration Ministry.

Idari yii lo wayẹ lẹyin ọrọ ti gbajugbaja adari ẹka ile ijọsin Aguda naa, Ejike Mbaka sọ wi pe Peter Obi, oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ko le e di aarẹ orilẹede Naijiria.

Ninu fidio to n ja ranyin lori ayelujara ni Father Mbaka ti ni Peter Obi kii ṣoore fun awọn eniyan.

Mbaka ni aahun to n kawọko ni Obi, ti ko si gbọdọ jẹ aarẹ Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti awọn adari naa fi sita fun awọn akoroyin, Bisọọbu Onaga ni oun kọ lilọ ile ijọsin Mbaka fun awọn olujọsin ijọ aguda.

O ni lẹyin ti Mbaka ti kọ lati tẹle ofin ati aṣẹ ijọ aguda ni o fi kede aṣẹ naa fun awọn olujọsin.

O tẹsiwaju pe ipinu naa lo waye lẹyin ọrọ ti Mbaka sọ si Peter Obi to jẹ gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ri ati oludije sipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party ninu eto idibo ọdun 2023.

aworan bisoobu enugu ati fr mbaka

Oríṣun àwòrán, screenshot

Òrò tí Mbaka sọ sí Peter Obi lòdì sí òfin ìjọ Aguda- Bisọ́ọ̀bù Enugu

Awọn adari ijọ aguda ni ipinlé Enugu ti ni oro ti gbajumo alufaa ninu ijó naa, Fr. Ejike Mbaka sọ si olidijẹ fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’, Peter Obi lodi si ofin to ro mo ijọ naa.

Bisọọbu ti Enugu, Ernest Anaezichukwu Obodo lo kede oro na sita fun awọn akoroyin ni ana.

Obodo ni irufẹ oro naa ni ko yẹ ko ma jade lenu ojisẹ ọlọrun

“A fẹ ki Fr Mnaka dẹkun lati ma sọ oro ti o le mu gbomisi omioto waye lorielede Naijira”

“A fi asiko ko yi sọ fin awọn ọmọ orilede Naijiria pẹ oro ti Mbaka so ni ki n se oro ijo aguda nitori pe o lodi si ofin ijọ naa”

O tẹsiwaju pe ijọ aguda ti gbe igbinmo kalẹ lati iwadi ati atunse lori oro ti Fr Mbaka sọ si ita.

Bisọọbu naa wa ro awọn ọmọ orilede Naijira lati yago fun iwa jagidijagagan lasiko eto idibo lọdun 2023.

Father Mbaka to jẹ adari ile ijọsin Adoration Ministry Enugu lo sọ ọrọ pe Peter Obi ti o jẹ gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹri le e di aarẹ orilẹede Naijiria.

2023 Presidential Election; Father Mbaka ní Peter Obi jẹ́ ahun ènìyàn tí ipò aàrẹ kò tọ́ sí

Peter Obi ati Ftaher Mbaka

Oríṣun àwòrán, Google

Gbajugbaja adari ẹka ile ijọsin Aguda , Ejike Mbaka ti sọ wi pe Peter Obi ko le e di aarẹ orilẹede Naijiria.

Father Mbaka to jẹ adari ile ijọsin Adoration Ministry Enugu lo sọ ọrọ naa lasiko eto adura to waye ni ile ijọsin naa.

 Peter Obi to ni gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹri lo n dije du ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’ ni Naijiria.

Ohun ti Father Mbaka sọ nipa Peter Obi ree…

Ninu fidio to n ja ranyin lori ayelujara ni Father Mbaka ti ni Peter Obi ko ni ẹmi imoore tabi isoore fun ẹnikẹni.

Mbaka ni alahun to n kawọko ni Obi, ti ko si gbọdọ jẹ aarẹ Naijiria.

‘’O dara lati ni aarẹ to jẹ agbalagba to lawọ, ju ki a ni aarẹ to jẹ ọmọde amọ ti ko lawọ rara.’’

‘’Ẹnu Peter Obi si n yọ nitori naa ko ni ibi kankan to n lọ, ayafi to ba wa kunlẹ lori pẹpẹ ile ijọsin Adoration.