Folarin ní wàhálà wà fún Makinde tó bá yọ igbákejì rẹ̀ nípò

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ nipinlẹ Ọyọ, Teslim Folarin ti ṣe ikilọ fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde, pe ko ma ni erongba lati gbiyanju pe oun fẹ yọ Igbakeji rẹ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan, to ti darapọ mọ ẹgbẹ APC nipo, nitori pe yoo da wahala silẹ fun un.
Fọlarin lo ṣe ikilọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ninu atesita kan ti oludamọran rẹ lori eto iroyin, YSO Adeniyi fi sita fun awọn akoroyin.
O ni gbogbo igbesẹ ati igbiyanju awọn aṣofin ti Ṣeyi Makinde ti pin owo fun ti wọn fẹ yọ Ọlaniyan ko ni ṣeeṣe rara nitori ida meji ninu mẹta awọn ọmọ igbimọ ni wọn gbọdọ fọwọ si iyọnipo naa.
O tẹsiwaju pe lara awọn aṣofin naa ti wọn ṣi ni ẹri ọkan, atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti wọn dibo yan ọkunrin naa lati lo ọdun mẹrin nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina ni yoo lodi si igbesẹ gomina naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
O ni iyansipo gomina yii ṣi wa labẹ ofin, ti ko si si ohunkohun to le ṣii nidii titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun to n bọ.
Awọn ọmọ ileegbimọ aṣọfin ipinlẹ Ọyọ l'Ọjọru, ọsẹ to pari yii, bẹrẹ igbesẹ lati yọ igbakeji gomina wọn naa, Rafiu Ọlaniyan nipo.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o hu awọn iwa ti ko tọ, o ṣe awọn owo kan to wa ni ikapa rẹ mọkumọku, aṣilo ipo to wa gẹgẹ bii igbakeji gomina, bẹẹ ni wọn tun sọ pe o fi ọfiisi ati iṣẹ to yẹ ko maa ṣe gẹgẹ bii igbakeji gomina silẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn aṣofin mẹrinlelogun ni wọn ti fọwọ si iyọnipo rẹ latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ilé aṣòfin Oyo bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ́ igbájejì gómìnà nípò
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti fi ẹsun marun un ọtọtọ kan igbakeji gomina ipinlẹ naa, Rauf Olaniyan.
Mẹrinlelogun ninu awọn aṣofin ile naa lo tọwọ bọwe ẹsun naa, eyii ti wọn ka ni gbagede ile ọhun lọjọru.
Gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe naa, lara ẹsun ti wọn fi kan Olaniyan ni aṣilo ọọfisi, iwa kobakungbe, ṣiṣi owo ilu na, aibọwọ fun awọn alaṣẹ, atawọn ẹsun mii.
Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn ka iwe ẹsun naa tan, agbẹnusọ ile ọhun, Adebo Ogundoyinbo sọ pe iwe naa wa ni ibamu lati bẹrẹ igbeṣe lati yọ Olaniyan nipo gẹgẹ bi igbakeji gomina ipinlẹ Oyo.
O fi kun pe ile aṣofin ọhun yoo fun Olaniyan ni ọjọ meje pere lati wa sọ tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan, bi bẹẹ kọ, awọn yoo bẹrẹ igbeṣe lati yẹ aga mọ nidi.

Oríṣun àwòrán, Oyo state house of assembly
Ọjọ meje ti wọn fun igbakeji gomina naa si ti bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, eyii ti yoo wa sopin lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.
Iwe ẹsun naa ni “Gbogbo ẹsun ti a fi kan ọ lo wa ni ibamu pẹlu abala 188 iwe ofin orilẹ-ede Naijiria, eyii ti wọn ṣe atunṣe si lọdun 2011.”
Awọn amofin to buwọlu iwe ẹsun naa
Awọn amofin to buwọlu iwe ẹsun naa ni: Fadeyi Muhammed latiOna Ara, Onaolapo Sanjo lati Ogbomosho South, Babalola Olasunkanmi latiEgbeda, Adebisi Yussuf latiIbadan Southwest 1, Okedoyin Julius lati Saki West, ati Adebayo Babajide latiIbadan North 2.
Bakan naa ni awọn wọnyii tun buwọlu iwe naa: Kehinde Olatunde lati Akinyele 2, Olajide Akintunde lati Lagelu, Mustapha Akeem lati Kajola, Popoola Ademola lati Ibadan South East 2, Owolabi Olusola lati Ibadan North East 2, Olagoke Olamide lati Ibadan North East 1, Olayanji Kazeem lati Irepo/Olorunsogo, ati Ojedokun Peter to n ṣoju Ibarapa North/Centre.
Awọn amofin to ku ni : Gbadamosi Saminu lati Saki East/Atisbo, Mabaje Adekunle lati Iddo, Oluwafowokanmi Oluwafemi lati Ibadan Southwest 2, Akeem Adedibu lati Iwajowa, Fatokun Ayo lati Akinyele 1, Rasak Ademola lati Ibadan South East 1, Obadara Akeem lati Ibadan North West, Oyekunle Fola lati Ibadan North 1 ati Adetunji Francis to n ṣoju fun Oluyole.












