Àwọn fídíò àtijọ́ tí wọ́n fẹ́ fi dá wàhálà sílẹ̀ ní Naijiria rèé

Olopaa

Oríṣun àwòrán, @AIT

Fact check: Àwọn fídíò àtijọ́ tí wọ́n fẹ́ fi dá wàhálà sílẹ̀ ní Naijiria rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ọpọlọpọ iroyin ẹlẹjẹ lo n kaakiri lori ọrọ aabo ni Naijiria ṣaaju idibo gbogboogbo ọdun 2023.

Awọn eniyan si n ṣe atunpin iroyin yii lori ẹrọ ayelujara, paapaa to niiṣe pẹlu ọrọ ẹsin ati ẹya.

Bakan naa lati igba ti iṣẹlẹ iṣekupani ninu ile ijọsin ti waye ni ilu Ọwọ ni orisirisi iroyin ofege ti n jẹyọ.

Ogoji eniyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ti eniyan to le ni aadota si farapai ni lori iṣẹlẹ naa.

Fidio awọn Fulani ọkunrin ati obinrin to gbe ibọn dani

Awọn ọmọ Naijiria n ṣe atunpin fidio to ṣafihan ọgọọrọ awọn ọkunrin ati obinrin to gbe ibọn dani ti wọn si n jo.

Ori Facebook ati Whatsapp ni wọn ti pin awọn fidio wọnyii ju igba ẹgbẹrun mẹfa lọ.

Ohun ti awọn eniyan ṣi n sọ ni pe awọn Fulani to gbe AK-47 dani ti ṣetan,nigba ti awọn ara Guusu gbe PVC dani.

Amọ iwadii fihan pe ko si otitọ nibẹ ati pe wọn kii ṣe Fulani amọ awọn ara Ethiopia ni wọn, ti wọn si n ja fun ẹtọ agbegbe wọn.

Fidio safihan ọkọ nla Dangote to gbe awọn Fulani lọ si iha Guusu Ila oorun

Iroyin ofege kan sọ wi pe ọkọ awọn Fulani lọgọọrọ to gbera lati Ariwa Naijiria lọ si iha Ila Guusu Naijiria, amọ ko si otitọ kankan nibẹ.

Iwadii fihan pe asiko ti ajakalẹ aarun Coronavirus peleke si ti ko si si lilọ- bibọ kaakiri agbaye.

Amọ ounjẹ nikan ni wọn n gbe lati Ariwa Naijiria wa si awọn agbegbe to ku.

Asiko igba naa ni wọn ya fidio naa lẹyin ti wọn mu awọn to farapamọ sinu ọkọ naa, ti ọlọpaa si n beere ibi ti wọn n lọ.

Ki gbogbo ṣọọṣi di titi pa fun oṣu mẹta nitori lẹta idunkooko mọni

Kaakiri ori ẹrọ ayelujara ni wọn ti n pin fidio ibi ti ọlọpaa kan ti n sọ fun awọn akoroyin pe awọn gba lẹta idunkoko mọni pe ki wọn ti gbogbo ile ijọsin pa fun oṣu mẹta ki wọn ma ba a pa wọn ru.

Amọ iwadii fihan pe iroyin ofege ni, tii kii si ṣe iṣẹlẹ to ṣẹṣẹ waye.

Ileeṣẹ ọlọpaa Zamfara lo gbe fidio naa jade ni Oṣu Kọkanla, ọdun 2021 lati le kilọ fun awọn eniyan nkan ti awọn agbebon n ṣe ni ipinlẹ naa.

Wọn ni ko si idunkooko kankan to jọ bẹẹ lasiko yii, nitori naa ki awọn eniyan fi ọkan balẹ.

Lati igba ti iṣẹlẹ iṣekupani ninu ile ijọsin ti waye ni ilu Ọwọ ni orisirisi iroyin ofege ti n jẹyọ.

Ogoji eniyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ti eniyan to le ni aadota si farapai ni lori iṣẹlẹ naa.