Kí ló fa gbas-gbos láàrín ìjọba àpapọ̀ àti Oyedepo?
Bishop Oyedepo àti Femi Adesina tahùn síra wọn lórí ibi tí Naijiria dé dúró

Oríṣun àwòrán, davidoyedepomin/mbuhari
Fa ki n fa ti n waye laarin ijọba apapọ Naijiria ati oludasilẹ ijọ Living Faith Church Worldwide, Biṣọọbu David Oyedepo.
Bi Oyedepo ṣe n bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ pe o ti kuna sawọn araalu ninu ojuṣe rẹ, naa ni ijọba apapọ n da padap fun alufaa naa.
Inu ṣọọṣi ni Oyedepo ti sọ oko ọrọ si ijọba ki ijọba to fesi pada loju opo Twitter.
Ki ni Oyedepo sọ?
Lasiko to n sọrọ lori pẹpẹ iwaasu rẹ lọjọ Aje, Oyedepo sọ pe ijọba Buhari lo buru ju, to tun ni iwa jẹgudujẹra julọ ninu itan ijọba to ti n tukọ Naijiria.
Oyedepo fẹsun kan ijọba apapọ pe ko kọbi ara si iya to n jẹ awọn araalu, paapaa awọn akẹkọọ lasiko yii.
Alufaa naa tun sọrọ lori bi wọn ṣe fẹsun kan oluṣiro agba Naijiria pe o ko ọgọrin biliọnu naira sapo labẹ ijọba Buhari, to si sọ pe obitibiti owo naa to lati gbọ bukata ẹgbẹ awọn olukọ fasiti Naijiria, ASUU, ti wọn ti yanṣẹlodi bayii fun nnkan bii oṣu mẹrin.
O ni “Ọpọ awọn akẹkọọ ni ko si nile ẹkọ bayii nitori ko si owo ti yoo da wọn pada sile ẹkọ wọn... A tilẹ ri awọn akẹkọọ kan ni fasiti Covenant ti a ran lọwọ lati kawe jade.”
“Awọn akẹkọọ to jafafa ko le ri ẹgbẹrun lọna ọgbọn pere labẹ ijọba buburu yii to jẹ pe ti ara rẹ nikan lo mọ.”
“Ijọba yii ni oun n gbogun ti iwa jẹgudujẹra amọ oluṣiro agba lu ọgọrin biliọnu naira ni ponpo ninu ijọba yii, nigba ti owo ti yoo gbe awọn akẹkọọ Naijriia pada sile ẹkọ to iye owo to ko jẹ... ijọba yii si ni oun n gbogun ti iwa ajẹbanu.”
Ijọba apapọ fesi
Nigba ti jọba apapọ yoo fesi, ijọba ni bi ẹni ti ko mọ ohun to n sọ lọrọ Oyedepo ri.
Agbẹnusọ Aarẹ, Femi Adesina sọ loju opo Twitter rẹ pe ọrọ ti Oyedepo sọ ko ṣeyin ikorira rẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni “Biṣọọbu to wa ni Ota yii ko mọ ohun to n sọ rara, o si yẹ ko ṣe iwadii ki ọrọ to maa jabọ lẹnu rẹ.”
“O ṣenu laanu pe mọ iyatọ to wa laarin oluṣiro agba ati ẹni to n yẹ iwe owo ti iojọba na wo.”
“Ohun to sọ nipa owo ti 80b to ni wọn kojẹ ko ṣeyin bo ṣe korira Aarẹ Buhari.”












