Africa Eye: Orúkọ Eṣu Dúdú ti wọ́n pé àwon ọmọdé aláwọ̀ dúdú nínú fídíò kan ní China di wà

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Orúkọ Eṣu Dúdú ti wọ́n pé àwon ọmọdé aláwọ̀ dúdú nínú fídíò kan ní China di wà

Bẹ́ẹ̀, Malawi ni ọ̀rọ̀ n bọ́rọ̀ lọ bayii lori iwadii fọnran fidio naa.

Ijóba Malawi ti fariga lori fọnran fidio naa pe o tabuku awọn ọdọmọde ni Malawi.

Patricia Kaliati to jẹ minista awọn akanda ẹda ati ọmọ wẹwẹ ati itọju wọn ni pe ohun itiju lo jé pe Malawi ni orisun fidio naa ko to de China.

O ni pe ijoba ti gbe ikọ iwadii dide lori fidio naa to jade logunjọ oṣu keji ọdun 2020.

Kini o wa ninu fidio naa?

Ninu fidio naa ni awọn ọmóde alawọ dudu kan ti n ka akọsori pẹlu ayọ pe : Esu dudu ni mi, ọpọlọ mi si kere ni ede Chineese

Fidio naa si fa wahala lasiko to gba ori ayelujara kan ni China.

Eyi lo mu ki awon osise ikọ iwadii BBC Africa Eye ṣiṣẹ iwadii yii.

Investigative reporters: Runako Celina and Henry Mhango

Producer: Chiara Francavilla

Video editing: Suzanne Vanhooymissen & Matthew Bradley

Exec Prod: Daniel Adamson