BBC Africa Eye: Ikọ̀ olùwádìí tú àṣírí ìfìyàjẹni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò
ÌKÌLỌ̀ PÀTÀKÌ: Fọnran yii ni aworan awọn nkan to lee ba ni lọkan jẹ atawọn aworan ifiyajẹni pupọ.
Akanṣe eto BBC Africa Eye ree, eyi to maa n tu aṣiri awọn nnkan ikọkọ tabi to farasin, to si n ṣakoba fun araalu ati ijọba.
Pẹlu awọn fidio to n ṣe aridaju awọn iṣẹlẹ yii ti wọn fi han, aṣiri tu sita pe, ifiyajẹni ti di aṣa ti ọpọlọpọ ẹka ileeṣẹ Ọlọpaa Naijira atawọn ologun n lo.
Akanṣe iwadii yii boju wo ibẹrẹ pẹpẹ aṣa ifiyajẹni awọn agbofinro yii, paapaa awọn ikọ ọlpaa SARS, to si foju awọn tọwọ wọn wa ninu rẹ ju han.
Bakan naa ni Afircan Eye lwadii idi ti wọn ko fi fi wọn jofin.