Africa eye: 300 mílíọ́nù dọ́là ni Gambia ń padánù sọ́wọ́ àwọn onífàyàwọ́ gẹdú

Àkọlé fídíò, Africa eye: Fàyàwọ̀ igi gẹdú ló ń wáyé ní Gambia àti Senegal

Gbogbo igi loko lo ni iwulo rẹ koda ọpọ igi lo jẹ igi owo fun ẹda.

Amọṣa bi ẹda ba wa n tipasẹ a n ta igi owo da ayika rẹ legbodo, nnkan yoo yan.

Lorilẹede Gambia ati Senegal, igi Apẹpẹ jẹ igi kan ti Eleduwa fi jinkin wọn ṣugbọn to ti di owo nla ati eyi ti gbogbo agbaye n wa kiri.

Eleyii si ti mu ki ọpọ agegẹdu o tori ere to wa ninu igi yii sọ ọpọlọpọ igbo di aṣalẹ.

Ninu iwadii ikọ African Eye loṣu yii, BBC news fimufinlẹ lori awọn iwa irufin to n waye lori gige ati tita awọn igi Apẹpẹ lorilẹede Gambia ati Senegal.