Africa Eye: Ọmọ ìgboro méje tó ń jò tà di aláṣeyọrí

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ọmọ ìgboro méje tó ń jò tà di aláṣeyọrí

Yoruba ni ẹni ti ko ba le se bi alaaru ni Oyingbo, ko le se bi Adegboro ni ọja ọba, ẹni ti yoo si ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin.

Owe yii lo ba awọn gende meje kan mu, ti wọn dagba soju popo lai ri isẹ oojọ kankan se, wọn ko nile lori bẹẹ naa si ni wọn ko ri ẹni fẹyin ti.

Awọn gende yii ko ri ọwọ mu lọ sẹnu, ti wọn si n gbe igbe aye wọn bi alaini ẹnikan, koda oju wọn n ri mabo loju popo ti wọn dagba si.

Àwọn iwadii ọtẹlẹmuyẹ Africa Eye tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ree ti ẹka iwadi ọtẹlẹmuyẹ BBC nilẹ Afirika se n tẹle wọn lẹyin lati finmu finlẹ mọ ibi ti ọrọ aye awọn gende meje naa yoo pada yọri si.

Amọ lẹyin ọdun meji, ori awọn ọmọ naa pada wa sọre, oju popo naa si ni wọn ti rinna pade oloore wọn.

Ijo jijo loju popo ti wọn yan laaye gbe wọn de ibi giga, ti wọn si kuro ni ojo popo.