Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Lojoojumọ ni Ahmed Isah, tii se olootu eto Bẹrẹkẹtẹ maa n ya awọn ọmọ Naijiria lẹnu pẹlu sna to n gba lati gba ẹtọ wọn le wọn lọwọ.

Ọna to n gba lati fidi ẹtọ ọmọniyan le wọn lọwọ yii ni eto rẹ naa to n se lori redio ati tẹlifisan, ti ọpọ eeyan maa n wo.

Ahmed, ti ọpọ eeyan mọ si ‘Ordinary President’, taa mọ si aarẹ lasan lasan ni ọpọ ọmọ Naijiria sọ di orisa nitori bo se n lo agbara rẹ lati gba ẹtọ mẹkunnu fun wọn.

Se lo maa n pe awọn oloselu nija lori afẹfẹ, to fi mọ ileesẹ ọlọpaa to maa n gbe wa siwaju awọn ọmọ Naijiria, eyi si mu ki ọpọ mẹkunnu nifẹ rẹ.

Akọroyin fun ẹka iroyin ọtẹlẹmuyẹ nilẹ Afirika, BBC Africa Eye, eyiun Peter Nkanga tọpinpin Ahmed Isah ati ikọ rẹ fun ọpọlọpọ ọsẹ.

Nibẹ si ni wọn ti sawari rẹ pe lootọ lo le jẹ aarẹ lasan lasan to n yi igbe aye ọpọ eeyan si rere amọ awọn ọna to n gba eyi to n mu awuyewuye lọwọ le mu ewu miran dani.