Africa Eye: Ọwọ́ tẹ dókítà Abdallah tó ń tà ayédèrú oògùn Coronavirus
Awọn miran n lo ajakalẹ arun Coronavirus lati fi pa owo wọle fun ara wọn lọna ti ko bofin mu.
Lara wọn ni Dokita Abdallah to n ta ayederu oogun Coronavirus fun awọn eniyan lorilẹede Ghana.
Ileeṣẹ BBC pẹlu akọroyin otẹlẹmuyẹ, Annas Aremeyaw Anas to ṣe iwadii awọn to n ta ayederu oogun Coronavirus ni ilẹ Ghana, fihan pe ọpọlọpọ wọn ko gba ontẹ ijọba.
Bakan naa ni awọn ayederu oogun naa tilẹ ni awọn kokoro aifojuri miran ninu to le ṣe eniyan leṣe tabi da aisan miran si ara eniyan.
Ẹkunrẹrẹ fidio naa ṣe afihan bi ọwọ ṣe tẹ dokita ayẹdẹru naa.