Africa Eye Sex workers: BBC tú àṣírí ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọ olóṣó
Lara awọn to n da gbe ni ibi ti wọn fi ṣe ibudo sọ fun BBC pe gbogbo nkan ti oju aṣẹwo n ri ko ṣee fẹnu sọ.
"Wọn ge atẹlẹsẹ rẹ, ati awọn ẹya ara mii". O n ṣalaye kan lara wn ti o kagbako iku ojiji. O ni ọpọ igba lawọn maa n bẹbẹ fun iranwọ.
Lara nkan aburu ti oju wọn maa n ri ni ẹka aṣewadii BBC tọpinpin iṣlẹ bi wọn ṣe pa oniṣẹ aṣẹwo kan ni Sierra Leone to ti di adiitu.

BBC tu aṣiri ibudo ti wọn fi ṣe iluu tiwọn nibi ti awọn obinrin ti n ta ta ibalopọ lati fi gba owo.
Tyson Conteh ni akọroyin to tẹ̀lé wọn kiri lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Pẹlu adari wọn, Lay P, wọn n ja fun ẹtọ wọn lati lee da duro.
Bo tilẹ jẹ wipe ofin ko faa gba iṣẹ nọbi ṣiṣe lorilẹede Sierra Leone, awọn obinrin naa ni wọn ri gẹgẹ awọn ti wọn ti tanu ti wọn kan n ri iranwọ kekeke gba lọwọ ijọba ati lawujọ.
