Igboho Vs Fulani: Ìjọba Oyo bẹ̀rẹ̀ ìtọjú àwọn èèyàn tó farapa nínú ikọlù darandaran ní Ibarapa

Aworan Sunday Igboho ati ikọ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Ọyọ, Dokita Bashir Bello ti ṣe alaye wi pe ẹka ileeṣẹ ijọba naa ti bẹrẹ itọju awọn eeyan mẹta ti o fi ara pa nibi ikọlu awọn darandaran ni agbegbe Igangan.

Ninu ọrọ ti Bello ba awọn oniroyin sọ nilu Ibadan lo ti fi idi ẹ mulẹ pe nile iwosan ijọba kan to n bẹ nilu Ibadan ni awọn eeyan naa ti n gba itọju lọwọlọwọ.

Bakan naa ni o fi kun ọrọ rẹ wi pe ara awọn eeyan naa ti n mokun.

Dokita Bello ṣe alaye wi pe ninu abẹwo to waye nilu Igangan lọsẹ ti o kọja ni Gomina Makinde ti paṣẹ wi pe ki wọn ko awọn eeyan to fi ara pa wa fun itọju nilu Ibadan.

O tẹsiwaju wi pe gomina ti paṣẹ fun ẹka eto ilera ipinlẹ Ọyọ lati tọju awọn eeyan naa ki wọn si gbọ gbogbo bukata to ba niṣe pẹlu itọju naa.

Atẹjade lati ọwọ akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Taiwo Adisa ṣe alaye siwaju si i wi pe gbogbo ayẹwo to yẹ ni wọn ti ṣe fun awọn eeyan naa.

O tẹsiwaju wi pe orukọ awọn eeyan naa ni; Isaiah Seun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn; Emmanuel Aderogba, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin; ati Adekola Adeyemo, ẹni ọdun marundinlaadọrin.

Gẹgẹ bi Dokita Bello ṣe sọ, gomina Ṣeyi Makinde ti mu ileri ti o ṣe ni ilu Igangan ṣe nipa awọn eeyan to fi ara pa nibi ikọlu awọn darandaran ni agbegbe naa.

Aworan Sunday Igboho ati ikọ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Olayinka Ọlayanju ti kede rẹ pe ilẹ Ibarapa ti bọ lọwọ awọn darandaran to n ṣekupa eeyan ati awọn ajinigbe.

Ọlayanju ṣe alaye ọrọ naa ninu atejade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin niluu Ibadan, pẹlu afikun wipe oun yoo fa ara oun kalẹ lati tẹle ẹnikẹni ti o ba nifẹ lati ṣe abẹwo si Ibarapa ki wọn le fi idi ọrọ mulẹ.

Fun idi eyi, o fi idanloju han lori alafia to ti n j'ọba ni awọn agbegbe ti awọn Fulani darandaran ati awọn ajinigbe ti n ṣoro bii agbọn tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: 'Ǹkan tÍ Sunday Igboho Ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun'

Adari ikọ Amọtẹkun naa koro oju si awọn oriṣiriṣi fọnran to gba ori ayelujara kan ninu eleyii to ni "awọn eeyan kan ti n sọ ohun ti oju wọn ko to lorii eto aabo ni agbegbe Ibarapa".

O ṣalaye wipe gbogbo agbegbe Ibarapa ni oun ti rin kaakiri laarin ọjọ melo kan bayii.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn agbẹ ati awọn eeyan ilu to n tẹle ofin ijọba ti n lọ si ẹnu iṣẹ oojọ wọn pada ni agbegbe naa laisi idunkukulaja mọ ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun