Fulani Herdsmen: Mi ò fì ìgbà kankan pe Sunday Igoho ní akọni- Wole Soyinka

Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti ni oun to n dẹru ba oun ju nipa wahala agbẹ ati darandaran ni pe o ṣeeṣe ki ọrọ naa di ogun abẹle.

Alagba Soyinka n fesi yi nigba to n ba ikọ BBC sọrọ lori wahala darandaran agbẹ to ti di rọnto lẹnu ọjọ mẹta yi ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ
Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka

O ni ija awọn mejeeji yi le di aawọ ti wọn yoo maa ṣe ara wọn leṣe ti o si le yiwọ di ogun abẹle.

Ọrọ Soyinka yi n waye ni kopẹ kopẹ bi Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ Onda naa ti ṣe paṣẹ ki awọn darandaran kuro ninu igbo ipinlẹ rẹ.

Soyinka ni '' A le bọ si ipo pe ki ija yi di eyi to mu ikọlu wa to si le di mi o fẹ sọ ọrọ yi ṣugbọn o le di ogun abẹle ti yoo buru jai''

Ayafi ti wọn ba gbe igbesẹ, o si dun mọ mi pe awọn Gomina kan ti gbe igbesẹ ti wọn si pe awọn Miyetti Allah da si ọrọ ki wọn si maa tẹle ofin''

Aworan ọjọgbọn Soyinka

Ọjọgbọn Soyinka ṣapejuwe awọn darandaran aṣekupani yi gẹgẹ bi ''ọta ti wọn n huwa bo ti ṣe wu wọn, wọn gbagbọ pe ko si ohun ti yoo tẹyin rẹ bọ''

O ni idi ree ti ''awọn ọmọ ologun ni ipinlẹ temi gaan alara fi n gbe lẹyin awọn ọta wọn yi''

Ọjọgbọn Wole Soyinka salaye pe oun n ri loju iwe royin pe oun pe Sunday Igboho ni akọni lori igbese to n gbe, Ọjọgbọn naa ni, ko si igba tabi asiko kan ti oun pe Sunday Igboho bẹẹ.

Sugbọn Sunday Igboho ti da si nkan to n sẹlẹ nipa ọna ti o mọ nitori iṣẹlẹ to n waye ti sun kan ogiri, lo se se bẹẹ.

Ó ni ó se pataki láti pe Sunday Igboho lati dawọ igbesẹ to n gbe duro, ìgbàgbọ si wa pe yoo gbọ.