Lekki toll gate: Iṣẹ̀ àtúnṣe ti bẹ̀rẹ̀ padà ní ibodè náà, àwọn ọ̀dọ́ sì ti ń gbèrò ìwọ́de ọ̀tun

Ọpọlọpọ awọn ọdọ Naijiria lo ti n kùn, ti wọn si n fi ibinu han lori bi igbimọ oluwadii ti ijọba ipinlẹ Eko yàn lati ṣe iwadii ọrọ rogbodiyan #ENDSARS ṣe sọ fun awọn alasẹ ẹnu ibode Lekki lati bẹrẹ ọrọ aje wọn pada. Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji ni awọn alasẹ ileesẹ naa Lekki Concession Company yọjú si Lekki Toll Gate. Akọroyin BBC to wa ni ibode naa sọ pe ko din ni oṣiṣẹ ileesẹ LCC mẹfa, to wa si ibẹ lati ṣe iṣẹ atunse.
- Ọba tó wàjà àmọ́ tí òkú rẹ̀ gbúdọ̀ jókòó sórí ìtẹ́ ṣáájú ìsìnkú
- À ṣé ara mi ni isó tí ń rùn, tí èmi náà ń ṣépè fún ẹni tí Jamiu Azeez ń sọ - Mama Ereko
- Ọlọ́pàá dá ọkùnrin méjì tó ń ní ìbálòpọ̀ ọkùnrin sọ́kùnrin padà sí ìlú abínibí wọn
- Ọ̀kan lára àwọn adarí rere la ó pé Sunday Igboho nílẹ̀ Yoruba - Oluwo
Ogúnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni awọn oṣiṣẹ alaabo yinbọn mọ awọn ọdọ kan to n ṣe iwọde tako ọwọ líle awọn ọlọpaa, ni Lekki Toll Gate. Jakejado agbaye si ni awọn eeyan ti bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa.
Ọpọlọpọ awọn ọdọ si lo ti n leri pe awọn yoo ṣe iwọde mii nitori àṣẹ igbimọ naa si awọn alasẹ LCC lati bẹrẹ isẹ pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Nibayii, wọn ti bẹrẹ si ni lo #OccupyLekkiTollGate lati fi idi ọrọ wọn mulẹ lori ayelujara. Ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2020, ni iroyin to n lọ sọ pe iwọde naa yoo waye. Wọn ni ko yẹ ki Lekki Toll Gate di ṣíṣí pada, lai jẹ pe idajọ waye lori bi awọn oṣiṣẹ alaabo ṣe 'pa awọn ọdọ' nibẹ lọdun to kọja. Lara awọn gbajumọ to ti bu ẹnu ẹtẹ lu ṣíṣí ibode Lekki pada ni akọrin takasufe, Peter Okoye, DJ Switch ti gbogbo ọrọ EndSARS ko ṣẹyin rẹ gan ko gbẹyin.

Oríṣun àwòrán, Peter Okoye Twitter

Oríṣun àwòrán, DJ Switch Twitter
O ni "ti idajọ ko ba waye, ko ni i si LCC. Koda, ki ẹ gbe akoso rẹ le Jesu lọwọ." Bakan naa ni DJ Switch ti iṣẹlẹ ọjọ naa ṣoju rẹ, ti bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba. Sugbọn ṣa, awọn ọdọ kan ko faramọ iwọde tuntun yii, ti awọn kan lara wọn si ti fẹ ẹ sọ di ija ẹlẹyamẹya. Awọn 'alatako' yii naa si ti bẹrẹ si ni lo#DemNoBornYourPapaWell.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Eyi to tumọ si pe ti wọn ba bi baba awọn to fẹ ṣe iwọde daa, ki wọn o jade. Bẹẹni awọn kan si ti n pàrọwà fun igun mejeeji lati gba alaafia laaye.
Kí lẹ tún fẹ́ kí LCC ṣe lẹ́yìn tí gbogbo iwádìí ti parí ní Toll Gate? - Segalink

Kíni idí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń bínú sí Segalink?
Ìgbẹ́sẹ̀ àpá kan àwọn ìgbìmọ̀ tó gbẹ́jọ́ ìfìyà jẹni ọlọ́pàá tó gbà pé kí LCC gba ètò Lekki Toll gate padà ti àwọn apákejì ìgbìmọ̀ náà sì ni àwọn kò gbà kìí ṣe ǹkan tuntun mọ́.
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ Naìjíríà ló korò ojú sí ìhà ti Segun Awosanya ti gbogbo eniyan mọ si Segalink kọ si ọrọ naa eyi to si bi ọpọ awọn ọmọ Naijiria ninu.
Ọpọ lo sọ pe kini idi ti Segalink yoo fi wa lara awọn tó ni ki wón gba LCC pada lẹyin gbogbo nkan to ti ṣẹlẹ ati pese ebi Segalink ni awọn mọ gẹgẹ bi ẹni to n gbogun ti iwa ifiyajẹni ọlọpaa lati ẹyin wa.
Kini awọn ọmọ Naijiria n sọ?
Ṣaaju ni iroyin ti sọ pe, Segalink ati awọn mẹrin miran ti fẹnuko lẹyin atotonu agbejọro Lekki Consessional Company (LCC) pe ki wọn ṣi Toll Gate.
Bakan naa ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe Adegboruna, Rinu ati awọn meji miiran naa kọ jalẹ pe awọn ko faramọ idajọ adajọ Doris Okuwobi to jẹ olori igbimọ ọhun.
Lójú opó twitter, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti gbanajẹ lori igbesẹ̀ Segalink. Botilẹ jẹ pe, Segalink n gbiyanju lati ṣalaye idi to fi fì si ibi to fì sí.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ" emi kii se ọta ara ilu, ṣugbọn ki ẹ to mọ ibi ti ọrọ n lọ, o ṣeeṣe ki ẹpa ma boro mọ.

Oríṣun àwòrán, Segalink

Oríṣun àwòrán, Segalink
Segalink fi kun un pé, báwo ni gbigba ilé iṣẹ naa laaye lati se abẹwo bi nkan se bajẹ to ni ile isẹ ọhun lẹyin ti gbogbo iwadii ti pari nibẹ se nise pẹlu titi i pa.

Oríṣun àwòrán, Segalink
Ṣùgbọ́n lori gbogbo alaye rẹ awọn ọmọ Naijiria sọ ẹdun ọkan wọn lori ọrọ naa.
Gbajugbaja oloṣelu to tun ti dije du ipo gomina ri nipinlẹ Eko, Babatude Gbadamọsi sọ loju opo twitter rẹ pe" Ti o ko ba si ni iha tiwa, ko si nkan ti mo le se ju pe ki n sọ pe o digboṣe lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Awon miran tilẹ ni pe o ti wọ inu oselu lo fa a to n huwa bẹẹ lati gbẹyin bẹbọ jẹ.
Ọpọ ni igbesẹ Segalink ba awọn lọkan jẹ gidigidi lẹyin gbogbo nkan to ti se latẹyin wa lati gbogun ti iwa ibajẹ ọlọpaa.
Yoruba bọ wọn ni kii buruburu ko ma ku ẹnikan mọni, awọn miran gba pe, kii se oju ti awujọ fi n wo ọrọ yii gan ni nkan to sẹlẹ.
Wọn ṣalaye awọn isẹ akin ti Segalink ti se latẹyin wa.

Oríṣun àwòrán, Aristodsavage

Oríṣun àwòrán, "daddy-aoo
Lekki Shootings: Iléeṣẹ Lekki Concession Company ti gbàkóso Lekki Toll gate padà lẹ́yìn ọ̀ṣẹ́ ìwọ́de EndSARS

Ọrọ di fa ki n fa a laarin awọn ọmọ igbimọ to n gbẹjọ yii lorii a fẹnuko, ao jọ fẹnuko kẹẹ to paṣẹ ki wọn ṣi ibode Lekki pada.
Igbimọ to n gbẹjọ awọn ẹsun iṣẹlẹ iwọde ENDSARS atawọn ẹsun mii to rọ mọ aṣemaṣe awọn agbofinro ni ipinlẹ Eko da ṣiṣe akoso ẹnu ibode Lekki pada fun oni nkan iyẹn Lekki Concession Company (LCC).
Alaga igbimọ naa, adajọ agba Doris Okuwobi lo pa aṣẹ yii pe ki ileeṣẹ LCC Ltd pada sidi iṣẹ wọn gẹgẹ bi alakoso ati oludari Lekki toll gate.
Adajọ yii atawọn mẹrin mii to jẹ ọmọ igbimọ ọhun lo jọ gbọ awuye yala eyi to gbe e lẹyin tabi lodi si iwe ipẹjọ ti agbẹjọro ileeṣẹ LCC Ltd, Demola Seriki pe ki wọn ṣi ẹnu ibode naa pada.
Eyi ni igba ikẹrin ti ileeṣẹ naa yoo kọwe ipẹjọ.
- Àwọn àgbà wo ló fọ́wọ́ ọlá gbá gbajúgbajà òṣèré Jamiu Afeez lójú tó ń wa ẹkún mu lóríi sinimá tó ṣe?
- Adebimpe gba omijé lójú Adedimeji, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí da Saheed àti Fathia pọ̀
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
- Ìdí tí mo fi kọ lẹ́tà sí Pa Josiah Akindayomi pé mi ò fẹ́ jẹ G.O nìyìí- Pasítọ Adeboye
Iṣẹlẹ ipaniyan ni ibode Lekki Toll Gate waye ni ipinlẹ eko lalẹ ogunjọ oṣu kẹwaa, ọdun 2020 nibi iwode End SARS eyi to si di manigbagbe kaakiri agbaye nipa orilẹede Naijiria.
Awọn ọmọ igbimọ ọhun mẹrin to jọ joko pẹlu adajọ agba Okuwobi ni Segun Awosanya ti ọpọlọpọ mọ si Segalink, Oluwatoyin Odusanya (Oludari Citizen's Right), DIG Taiwo Lakanu to ṣoju ileeṣẹ Ọlọpaa ati Lucas Koyejo lati ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria.
Ninu itakurọsọ rẹ, Ọgbẹni Seriki pe ki igbimọ naa gba ileeṣẹ ọhun laye lati gbakoso Lekki Toll Gate nitori atile bojuwo iye adanu to ṣẹl nibẹ ki wọn lee lo eto adojutofo lati ṣe atunṣe ohun to ti bajẹ eyi ti wọn si ni yoo gba oṣu meji.
Lẹyin ti ẹjọ naa gbe e ni Agbẹjọro Agba Naijiria kan, Ebun-Olu Adegboruwa wọle pẹlu awọn ọmọ igbimọ mẹta mii, Patience Udoh to n ṣoju araalu, Rinuola Oduola ati Temitope Majkodunmu ti awọn mejeji jẹ aṣoju ọdọ.
Lọgan si ni gbogbo wọn gbe ọrọ to lodi si ohun ti wọn ti sọ siwaju wọn pe awọn ko ti aṣẹ ti wọn pa lẹyin o pe ki oni nkan gba nkan ati pe ki wn tun ṣi ẹnu ibode Lekki pada. Wọn ni laa, awọn ko gba.

















