Nigeria's Lekki EndSars Shooting: Ohun tó tí ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìjókò Igbìmọ̀ ìwádìí ikọlù Lekki

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Isẹlẹ iyinbọnpaniyan to waye loṣu to kọja ni Lekki Tollgate lasiko iwọde ENDSARS nilu Eko lọpọ kaakiri agbaye ti bẹnu atẹ lu.
Yatọ si pe wọn jijọ gba pe wọn yinbọn nibẹ, awọn oluwọde ati agbofinro Naijiria ko fẹnuko lori ohun to ṣẹlẹ ni pato lalẹ ọjọ naa.
Ireti ni pe agbekalẹ igbimọ iwadii yoo yanju ọrọ naa paapa eyi to ni ṣe pẹlu iwa ipa lati ọdọ awọn ọlọpaa si araalu.
Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ titi di bi a ṣe n sọrọ yi.
Awọn akọroyin wa to wa ni Eko n jabọ fun wa bi nkan ti ṣe n lọ nibi ijoko igbimọ iwadii ti ijọba gbe kalẹ lati tọ pinpin ọrọ yi.
- A dúro bí iké lẹ́yìn ìròyìn táa gbé jáde nípa Lekki Tollgate; CNN tako Lai Mohammed
- Àwọn tó mọ̀ nípa ìpànìyàn Lekki yóò fojú winá òfin - Sanwo-Olu sí Becky Anderson
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
Talo paṣẹ fawọn ọmọogun pe ki wọn lọ si Lekki Toll Gate?
Yiyọju awọn ologun ni Toll Gate Lekki lasiko iwọde alalaafia ko dun mọ ọpọ ninu ti wọn si ti n beere pe talo paṣẹ ki wọn lọ sibẹ? ni ibeere nla lasiko yii.
Gomina Babajide Sanwo-Olu Eko logunjọ oṣu Kẹwaa paṣẹ konile-o-gbele lati dẹkun ikọlu to n waye lawọn agbegbe kan ni Eko latari iwọde ENDSARS.
Saaju asiko yii ti iwọde naa n lọ laisi wahala ni awọn janduku kan gba a sii

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wakati diẹ lẹyin to paṣẹ yi, awọn ọmọogun de si Lekki Tollgate nibi tawọn oluwọde patẹ si lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
Ni idahun si idi ti awọn ologun fi wa nibẹ, Gomina Sanwo-Olu sọ fun ileeṣẹ iroyin Arise TV ni ọjọ Kejilelogun, oṣu Kẹwaa pe oun ko lagbara lati paṣẹ ki awọn ologun lọ si aaye iwọde.
Amọ, ileeṣẹ ologun sọ fun igbimọ iwadii lọjọ Kọkanla, oṣu Kọkanla, pe Sanwo-Olu lo pe awọn lati wa sibẹ.
Ọgagun Ahmed Taiwo ni Sanwo-Olu funrarẹ lo pe awọn lati wa sibẹ nitori ipa awọn ọlọpaa ko ka ohun to n ṣẹlẹ.
Nibi ijoko igbimọ naa omiran to waye lọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kọkanla ni aṣoju ologun to wa nibẹ ni iṣẹ ti wọn bẹ awọn kii ṣe lati tu awọn oluwọde ka.
Bi ko ṣe pe ki ''awọn da alaafia pada si agbegbe Eti-Osa nibi ti Lekki Toll gate wa''
Gomina Sanwo-Olu ko ti i fesi sọrọ tawọn ologun sọ.
Ṣe awọn ologun yinbọn to ni ọta ni tootọ abi bẹẹkọ?
Ọpọ ẹsun ni awọn eeyan ti fi kan ọlọpaa ati ologun pe wọn yinbọn ọlọta lu awọn oluwọde.
Ajọ ajafẹtọmoniyan Amnesty Internnational sọ pe eeyan mejila lo ku.
Nigba ti igbimọ iwadii yoo fi bẹrẹ ijoko ileeṣẹ ologun lawọn ko yinbọn lu ẹnikankan ati pe ọta ti ko loro lawọn yin ni Lekki Toll Gate lu awọn oluwọde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Kokanlelogun, oṣu Kọkanla ni ọgagun Taiwo sọ fun igbimọ naa pe awọn ọmọ ogun gbe ọta to loro ati eyi ti ko ni lọwọ.
Wọn ni idi ni pe awọn janduku ti darapọ mọ iwọde naa lati fi da nkan ru.
Lasiko ifọrọwanilẹnuwo, aṣoju ologun yi ni awọn janduku sọ oko lu awọn ologun to n kaakiri lagbegbe Oriental Hotel ki eeyan to de Lekki Toll Gate.
Ọmọoogun kan,gẹgẹ bi o ti ṣe wi, farapa.
O ni: ''Ki a to de Oriental Hotel ni wọn ti n sọ oko lu awọn ọmọogun ti wọn si fi ọta ti ko loro dawọn lohun pada.
Wọn ṣe ọmọogun kan leṣe, Okuta ba a ni ete rẹ.
Ti wọn ba sọ oko luwa, ohun ti a le fi da wọn lohun pada ni ọta ibọn ti ko loro.''
Ki lohun ti BBC jabọ?
Lọpọ ijoko igbimọ ati lawọn igba mii ti wọn ba awọn akọroyin sọrọ, ileeṣẹ ologun n sọ pe BBC jẹri si i pe awọn yinbọn soke ni ati pe awọn ko yinbọn lu awọn oluwọde.
Akọroyin BBC Pidgin, Damilola Banjo ninu iroyin to fi sọwọ ṣapejuwe ohun ti oju rẹ ri ni Lekki lasiko to wa nibẹ.
Kini Damilola Banjọ sọ?
Damilola ni oun kuro nibi ikọlu naa lẹyin nkan bi iṣẹju marundinlọgbọn jabọ pe:
"Ki a to kuro ni Lekki, awọn ologun n yinbọn soke ti a si sa asala fun ẹmi wa.
Mo ri arakunrin kan ti ko le e mi daadaa''
" Mo lero pe ohun to fa eyi ni pe aya rẹ n ja nitori bi awọn ologun ṣe n yinbọn leralera ati pe gbogbo ayika ibẹ ni ko rọgbọ''
''Wọn tẹ siwaju lati maa yinbọn fun nkan bi ogun iṣẹju ti a si daya delẹ ki awọn eeyan ma ba a tẹwa mọlẹ.
Ọga mi ti a jijọ wa nibẹ sunmọ awọn ologun, to si sọ fun wọn pe akọroyin ni wa ki wọn to jẹ ki a jade lalaafia.
O to nkan bi ogun si iṣẹju marundinlọgbọn ki a to ribi jade''
Ta lo pa CCTV?
Ọrọ miran to tun mu awuyewuye wa ni ti CCTV ti a mọ si kamẹra to ka ohun to waye nibi ikọlu Lekki lalẹ ikọlu naa silẹ.
Lasiko to n jẹri niwaju igbimọ ọga ileeṣẹ Lekki Concession Company to n mojuto Toll Gate, Abayomi Omomuwasan, sọ pe kamẹra naa sinmi lati maa ṣiṣẹ ni nkan bi aago mẹjọ alẹ
Ninu idahun rẹ si ẹsun pe wọn mọọmọ pa ina lasiko ikọlu naa, ọgbẹni Omomuwasan sọ pe nitori aṣẹ konileogbele ti ijọba gbe kalẹ lawọn fi ni kawọn oṣiṣẹ awọn maa lọ sile.
Nitori eyi o ni wọn ko le tan ẹrọ amunawa lẹyin igba ti ina ọba lọ.
Eeyan meloo lo ku?
Gomina Sanwo-Olu sọ fun CNN ni idahun si ibeere yi pe oku meji lo wa ni ile igbokupamọ si to si ni ki awọn araalu mu ẹri wa tabi ki wọn yọju ti wọn ba padanu mọlẹbi ninu iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ni awọn ko pa ẹnikankan ni Lekki Toll Gate.
Ọgagun Taiwo sọ fun igbimọ naa pe eeyan kan ku lopopona Admiralty Road ati pe iku rẹ ko waye latari iṣẹlẹ Lekki.
O ni awọn ọlọpaa naa gbe oku eeyan kan wa lati adugbo Yaba nilu Eko bakan naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Titi di igba wo ni igbimọ yoo fi joko?
Adajọ fẹyinti Doris Okuwobi lo n dari igbimọ yi.
Awọn mii to pẹlu rẹ wa lati ajọ ajafẹtọmoniyan, ajọ to n mojuto ẹtọọmoniyan ni Naijiria, Human Rights Commission, Citizens Mediation Centre ati awọn aṣoju ọdọ meji.
O ti le ni iwe ifẹhonuhan ọgọrun un le ni mẹwaa ti igbimọ naa ti gba.
Ireti wa pe wọn yoo gbọ gbogbo ẹsun yi nisoju awọn agbẹjọro ati awọn olujẹri.
Igbimọ ẹlẹni mẹjọ yii bẹrẹ lọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ti wọn yoo si fi oṣu mẹfa ṣe iwadii lati gbẹjọ ifiyajẹniyan lọwọ ọlọpaa lọna aitọ.
Bẹẹ naa ni wọn yoo daba ijiya to ba tọ fawọn ọlọpaa to ṣe aṣemaṣẹ pẹlu owo gba ma binu to ba tọ si awọn ti wọn fiya jẹ lọna aitọ.















