EndSARS Protest Update: Tunde Bakare ní ìwọ́de ọ̀dọ̀ jẹ́ ìparí sáà kan àti ìbẹ̀rẹ̀ òmíràn

Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Tunde bakare

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oluṣọ-agutan ijọ Latter Rain, Tunde Bakare ti sọrọ fun igba akọkọ lori iwọde EndSARS ati rogbodiyan to tẹle.

Ninu ọrọ to bawọn ọmọ Naijiria sọ, eyi to fi soju opo Twitter rẹ l'Ọjọbọ ni Bakare ti bọhun nipa iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

Bakare ni asia orileede Naijiria ti ni abawọn ẹjẹ awọn ọmọ wa pẹlu ikọlu tàwọn ologun ṣe sáwọn oluwọde ni Lekki.

"Abala keji orin ibilẹ Naijiria lo ni a o fi asia ailabawọn le awọn ọmọ wa lọwọ amọ o ṣe ni laanu pe Asia to ni abawọn ẹjẹ wọn, la fẹ gbe le wọn lọwọ".

Oluṣọ-agutan ìjọ Latter Rain fikun pe iwọde EndSARS to waye jẹ ipari iran kan lorilẹ-ede Naijiria ati ibẹrẹ iran miran.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni iwọde naa jẹ ifarahan ibẹrẹ orile-ede Naijiria tuntun ati ifehonuhan awọn araalu ti wọn n pe ni eeyan lasan.

Àkọlé fídíò, Àjẹ́ ké lánàá, ọmọ kú lónìí ni ọ̀rọ̀ Tinubu àti ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate - Bode George

" Iwọde EndSARS lo fi da mi loju pe iran tuntun ni Naijiria ti dìde, ti wọn fi isọkan sọrọ, ti wọn ko si gba ki wọn pa ina wọn tabi fi ọwọ bo wọn lẹnu tori asiko SọrọSoke la wa yii."

Nigba to n ṣe iranti ikọọkan awọn eeyan to ku lati ọwọ ọlọpaa SARS ati lasiko iwọde, Bakare wa kesi ijọba lati fi imu awọn ologun to kọlu oluwọde ni Lekki danrin.

Bakan naa lo tun rọ ijọba lati ṣe amusẹ ibeere awọn ọdọ, ki iku awọn oloogbe ma ba a ja si asan.