Nigeria Looting: Àwọn jàǹdùkú dárà, ẹ wo àwòrán àwòdamiẹnu nǹkan tí wọ́n jí gbé

Awodamiẹnu ni aworan awọn janduku to yabo awọn ipinlẹ Naijiria ti wọn si ji nkan orisirisi gbe.

Aworan ẹrọ amomitutu

Oríṣun àwòrán, Yemi Akintunde

Àkọlé àwòrán, Adugbo Alagbado nilu Ilorin lawọn janduku da firiiji nla yi pada si lẹyin ihalẹ ọlọpaa
Aworan ẹrọ ayẹwo ara ti awọn janduku ji gbe

Oríṣun àwòrán, onogwuMuha

Àkọlé àwòrán, Ni ilu Lokoja, awọn janduku ko tilẹ ṣaanu awọn ile iwosan nibi ti wọn ti gbe ẹrọ ayẹwo ara yi.
Aworan ẹrọ ayẹwo ara ti awọn janduku ji gbe

Oríṣun àwòrán, onogwuMuha

Àkọlé àwòrán, Ti pali ti pali ni wọn ji ẹrọ ayẹwo ara olowoiyebiye yi gbe bakan naa ni Lokoja
Aworan ẹrọ ikọlẹ(Tractor)

Oríṣun àwòrán, afamefuna.chidume

Àkọlé àwòrán, Haba! aduru ẹru yi ni igbe tawọn eeyan mu bẹnu nigba ti wọn ri aworan yi to wa lati Yola
Aworan ẹrọ ikọlẹ(Tractor)

Oríṣun àwòrán, afamefuna.chidume

Àkọlé àwòrán, Ohun to ṣẹku ree lara ẹrọ ikọlẹ (Tractor) lẹyin ti awọn alaburu ṣe apata rẹ tan ni Yola
Awoan awọn to ji nkan gbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Apo iresi,semo, ati pali indomie wa lara ohun ti wọn fi bẹrẹ ki ọpọn tosun siwaju
Aworan awọn to ji nkan gbe

Oríṣun àwòrán, ejiofor.agada

Àkọlé àwòrán, Ẹ ma damu jina maa wa Jalingo ka, arakunrin yi lo ji odidi olu ilu Taraba gbe
Aworan awọn to ji nkan gbe

Oríṣun àwòrán, emmanuel.majebi

Àkọlé àwòrán, Awo igbọnsẹ naa ko ribi bọ lọwọ awọn janduku...Hmmm
Aworan awọn to ji nkan gbe

Oríṣun àwòrán, emmanuel.majebi

Àkọlé àwòrán, Alupupu naa n gbe alupupu pọn lara ohun ti oju wa ri lasiko tawọn janduku yabo igboro
Aworan awọn to ji ami idanimọ ile aṣofin ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, ZurielOlowe

Àkọlé àwòrán, Ki la o ti ṣe eyi si o Ekiti kete!