Africa Eye Kenya blood sucking road: Àṣírí àwọn ọ̀nà mùjẹ̀-mùjẹ̀ tú! 'À ò kí ń mọ̀ bóyá a ó padà sílé táa bá jáde'

Àkọlé fídíò, Africa Eye Kenya blood sucking road: Àṣírí àwọn ọ̀nà mùjẹ̀-mùjẹ̀ tú! 'À ò kí ń mọ̀ bóyá a

Awọn ọkọ "ẹ tii ẹ rọmi sii pọ ju loju popo yii". Awọn fidio ti akọroyin ẹka ọtẹlẹmuyẹ BBC, Africa Eye ṣe fihan pe ọpọ ọkọ to wa loju popo lo yẹ ko ti gun ori odo.

Ikọ naa ṣe iwadii abẹnu lati tu aṣiri iwa ajẹbanu ati ijakulẹ oriṣiriṣi ti awọn eeyan n ba pade lọwọ ẹka to n ri si abo oju ọna ni Kenya.

Akọsilẹ fihan pe laarin ọdun 2020 si 2021 nikan, iku oju popo ni Kenya tun goke ju ida ogun lọ. Lọdun to kọja nikan, o ju eeyan ẹgbẹrun mẹrin abọ lọ to ku ti o si le ni ẹgbẹrun mẹrindinlogun to farapa.

Ẹwẹ, ijọba orilẹede Kenya ni mimu ọti lasiko ti wọn n wa ọkọ, ero ati ẹru akoju, ere asapajude lo pọ ju lara nkan to n fa iṣẹlẹ aburu yii. Amọ njẹ iwa ajẹbanu naa kun un?

Eyi ni ikọ Africa Eye tu aṣiri paapaa nipa awọn ile ẹkọ ọkọ wiwa to n gba owo lati fun awọn awakọ ti ko la eto ẹkọ kọja ni iwe ẹri "o yege".

Fun idi eyi, BBC Africa Eye tu aṣiri awọn ile ẹkọ ọkọ wiwa to n gbe awọn eeyan fo ilana to tọ ti wọn si n gba iwe ẹri lati lọ wa ọkọ.