Timothy Adegoke Vs Ramon Adedoyin: Olúwa mi, èmi ò ní ẹjọ́ kankan láti jẹ́ - Adedoyin tẹ̀ẹ́ pa nílé ẹjọ́

Lori ẹjọ oloogbe Timothy Adégòkè to ku si ile itura Hilton Hotel tii ṣe ti Oloye Ramon Adedoyin, ilé ẹjọ́ ti sún ẹjọ́ naa síwaju di ọjọ́ Ẹtì ọsẹ.
Ilé ẹjọ́ gíga Ìpínlẹ̀ Ọsun sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú tó pa arákùnrin Timothy sì ọjọ́ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí lẹ́yìn tí àwọn agbẹjọro fún olùjẹ̀jọ́ sọ fún ilé ẹjọ́ wípé àwọn ò ní ẹjọ́ kankan jẹ́.

Agbẹjọ́rò Yusuf Alli to jẹ agbẹjọro fun idile Adedoyin sọ fún Adájọ́ Adepele Ojo wí pé kí wọ́n fún àwọn ni wákàtí mejidinlaadọta láti gbé ìwé a kó ni ẹjọ jẹ wá sí iwájú ilé ẹjọ́.
Adájọ́ Adepele Ojo wá ní òun sún ẹjọ́ náà si ọjọ Ẹtí láti fún wọn ní afani lati gba iwe naa ki ilé ẹjọ sì wo o fini-fini.
Ṣaaju ni Dokita onimọ nipa ayẹwo oku ati nkan to ba ṣokunfa iku naa wa jẹri niwaju ile ẹjọ amọ ṣe ni Dokita naa kan gbe iwe iwadii rẹ silẹ lai ṣalaye faraye nipa abajade rẹ.
Ki ni "iwe a ko ni ẹjọ jẹ" tumọ si?

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn agbẹjọro to fara han nile ẹjọ ni alaye hande ohun ti itumọ nkan tawọn agbẹjọro Adedoyin n beere fun jẹ.
Ìwé "a ko ní ẹjọ jẹ ni o le fún àwọn afurasi naa ni afani lati maa jẹjọ lati Ile wọn" ṣùgbọ́n iroyin to to wa leti ni pe agbẹjọro ijọba, M.O Omashun ni oun ṣe tán láti fi esi sì ibeere naa ni ọjọ́ Ẹti.
Omashun ṣàlàyé pé ọpọlọpọ ẹlẹri lo wà ní ilé ẹjọ tí ko le fi àyè sílè pé ki àwọn akẹgbẹ rẹ ni àwọn kò ni ẹjọ kankan jẹ mọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe ohun ti ẹjọ yii da le lori gan ni pe arakunrin Timothy Adegoke to jẹ akẹkọ ipele Masters ni Fasiti Obafemi Awolowo, Ile Ife gba yara si ile itura Hilton to jẹ ti Ramon Adedoyin amọ ti iroyin iku Timothy ninu ile itura naa gbode kan.
Ẹbi Timothy si ti ni awọn n fẹ idajọ ododo latigba naa.


















