6 die at carnival auto crash: Bí èèyàn mẹ́fà ṣe kú lẹ́yìn tí ọkọ̀ yà wọ àárín èrò tó ń ṣe òde kánífà

Women react as they embrace each other after the attack

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan, eeyan mẹfa lo ti kagbako iku ojiji lẹyin ti ọkọ kan ya bara, to si kọlu ọpọ ero ti wọn n wo kanifa ni iha Guusu orilẹ-ede Belgium.

Iṣẹlẹ naa waye ni ilu kekere kan ti orukọ rẹ n jẹ Strépy-Bracquegnies, ti ko ju aadọta kilomita si ilu Brussels, to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa lọ.

Iroyin ni ọkọ ọhun rọ lu awọn eeyan to n mura lati kopa ninu lanifa naa laarọ ọjọ Aiku.

Gomina ipinlẹ ilu naa sọ pe nnkan bii ogoji eeyan lo farapa, nigba ti ọpọ awọn mii wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

O ni "Nnkan bii aadọjọ si igba eeyan lo wa nibi kanifa naa ki awakọ naa to kọlu wọn lati ẹyin to si wọ aarin wọn lọ."

"Lẹyin naa ni awakọ ọhun wa ọkọ naa fun nnkann bii ọgọrun mita siwaju ko to duro.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii ṣo eredi ti awakọ naa ṣe ṣe ohun to ṣe, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iṣẹlẹ ọhun kii ṣe iṣẹ ọwọ awọn agbesumọmi.

Àkọlé fídíò, Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Cristina Lanoco sọ fun BBC pe ijamba naa jẹ eyii to ba awọn ninu jẹ gidi.

O fi kun pe awọn ti fi awakọ naa atawọn eeyan to wa pẹlu rẹ si atimọle.

Ọlọpaa naa fi kun pe kii ṣe pe ijamba ọhun waye nitori awọn ọlọpaa n le awakọ rẹ gẹgẹ bii awọn iroyin kan ṣe sọ 0ṣaaju.

Olootu ijọba orilkẹ-ede naa, Alexander De Croo ti ṣabẹwo sibẹ.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo