Child abuse: Bàbá ẹni ọdún 60 bá ọmọ ọdún méjìlá tó jẹ́ adití àti odi lòpọ̀, ó dèrò àtìmọ́lé

child abuse

Ile ẹjọ kan ni Port Harcourt ti ni ki baba ẹni ọgọta ọdun kan lọ logba ninu ẹwọn titi di ọla ode yii lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o fipa ba ọmọ ọdun mejila kan to jẹ odi lopọ.

Ṣaaju ni baba ọmọ naa ti kọkọ bẹ ile ẹjọ ọhun ko boju aanu wo oun ki oun le ri idajọ ododo gba lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ẹka ileeṣẹẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdaran, SCID, to wa niluu Port Harcoourt lo pe Afurasi naa lẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan ki adajọ majistreeti naa to ni ki wọn fi si ahamọ lọgba ẹwọn titi di ọjọ Aje ti yoo bẹrẹ igbẹjọ rẹ.

Bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa

Baba ọmọ ti afurasi ọhun ba lopọ, Eze Eleonu sọ pe korokoro bayii ni ọwọ oun tẹ afurasi naa ni ihoho ọmọluabi pẹlu ọmọ oun.

O ni inu ile oun ni ọwọ oun ti tẹ pẹlu ọmọ oun lọjọ karun un, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Eleonu sọ pe ni kete ti oun ri bayii ni oun kigbe ibosi ara adugbo, ti awọn eeyan si ku giri wa sibẹ.

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun

Lẹyin naa ni wọn fa a le fijilante lọwọ, ti awọn naa si mu lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ubima.

Ijiya biba ọmọde lopọ

Ni Naijiria, ẹṣẹ ni labẹ ofin lati ba ọmọde ti ọjọ ori rẹ ko tii ju ọdun mejidinlogun lọ lopọ.

Ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun naa le fi ẹwọn gbere jura.

Amọ, yatọ si ẹwọn gbere, awọn ipinlẹ ni Naijiria naa ni oniruru ijiya fun ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, Iya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!