D’Banj ní àwẹ̀ àti àdúrà ló gbé òun dé orí ètò 'Nigerian idol' gẹ́gẹ́ bíi alákòso

Oríṣun àwòrán, iambangalee
Gbajugbaja olorin takasufe, D'Banj ti sọ pe adura ati awẹ lo gbe oun de ipo ọkan lara awọn adajọ lori eto Nigerian Idol to n lọ lọwọ.
Inu oṣu Kinni, ọdun 2022 yii ni awọn alaṣẹ eto naa kede D'Banj, Simi atawọn mii gẹgẹ bii dajọ lori eto ọhun.
Ninu ọrọ akọsọ rẹ nigba to de ori eto naa, o ni idunnu nla lo jẹ fun oun pe oun jẹ ọkan lara awọn adajọ lori eto naa ni saa yii.
- Wo àwọn àṣìṣe ikọ̀ ológun Russia ní Ukraine
- Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa Da Rocha, olówó yalumọ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yorùbá
- Ife omi há sí ilé ìtọ̀ obìnrin kan fún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tó fẹ́ fi gba adùn ìbálòpọ̀
- Bí orísùn ìkùnsínú ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin Ebele Obiano àti Bianca Ojukwu rèé
- Wo ìlú tí wọ́n ti ń gbé òkú ọba wọn pọ̀n lórí ẹṣin lọ fún ìsìnkú nínú igbó
- Ológun ní kí aya mi bọ́ aṣọ kúrò lára, pa ọmọ mi mẹ́rin àtàwọn alátìlẹyìn mi - El Zakzaky
- Wo àwọn gómìnà ọgbọ̀n tó ti kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn àjẹbánu àti àṣìlò ipò
- Sé lóòtọ́ọ́ ní ọlọ́pàá yìnbọn mọ́ àgùnbánirọ̀ n'Ibadan?
Lọjọ naa lọhun, o ni "Oke okun ni mo wa nigba ti mo gbọ pe wọn ti yan mi gẹgẹ bii ọkan lara wọn adajọ eto naa, mi o le fi ayọ ti mọ ni lọjọ naa pamọ."
Ninu fidio kan to n milẹ titi bayii lori ayelujara ni D'Banj ti sọ fun akẹgbẹ rẹ, Omawumi pe adura ati awẹ lori lo mu ki oun pegede lati de ori eto naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Omawumi bere lọwọ rẹ bo ṣe mọ oluṣoagutan kan to maa n gbadura lori ayelujara lọjọjọ Aje si ọjọ Ẹti, iyẹn pasitọ Jerry Eze atawọn ẹmẹwa rẹ, lori eto adura kan ti wọn n pe ni NSPPD.
D'Banj ni oun ni ibaṣepọ pẹlu pasitọ naa, ati pe ṣọọṣi rẹ gan ni oun lọ, oun ko si sinmi adura titi ti oun fi dero ori eto Nigerian idol naa.
O ni "Ijọ mi niyẹn o! Bawo lo ro pe mo ṣe de ori eto yii? A gba awẹ gidi gan!"
"Ọjọ keji ni wọn ke si mi pe wọn n fẹ ki n darapọ mọ eto naa."
"Lẹyin naa ni mo ni ko si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe."
Eto wo ni Nigerian idol?
Eto Nigeria idol jẹ ọkan lara awọn eto Idol to gbajumọ kaakiri agbaye.
Ọdun 2010 ni eto naa kọkọ gori afẹfẹ, ti wọn si ṣafihan rẹ ni ori ikanni marundinlogun kaakiri ilẹ Afrika.
Orukọ ẹni to kọkọ jaweolubori ninu eto Nigerian idol ni Onyekachi Elizabeth Gilbert Onwuka ti ọpọ mọ si "yeka onka" lati Ohafia.
Ẹbun owo miliọnu meje abọ lo fi ṣara rindin, to fo mọ ọkọ ayọkẹlẹ atawọn ẹbun mii.














