Sex Toy: Ife omi há sí ilé ìtọ̀ obìnrin kan fún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tó fẹ́ fi gba adùn ìbálòpọ̀

Ife omi yii ni wọn ba ninu ile itọ arabinrin naa, lai si ohunkohun to ṣe e

Oríṣun àwòrán, Thesun.co.uk

Àkọlé àwòrán, Ife omi yii ni wọn ba ninu ile itọ arabinrin naa, lai si ohunkohun to ṣe e

Ara me e riri, mo ri ori oloogbo lori atẹ. Ariwo ha, ko jẹ jẹ bẹẹ lo gba ẹnu awọn dokita nileewosan lẹyin ti wọn ri i pe gilaasi imumi lo wa ninu ile itọ obinrin kan.

Arabinrin ẹni ọdun marunlelogoji ọhun lo ti wa ninu irora fun ọdun mẹrin, to si n paara ileewosan.

Amọ wọn ko mọ aarun to n ṣe e.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to de ileewosan miranarun UTI lo sọ fun wọn pe o n sẹ oun, nigba to de ileewosan naa, nitori awọn apẹẹrẹ to n ri, paapaa, bi itọ ṣe ma n rin jade ni ara rẹ.

Akọsilẹ nnkan ti obinrin yii koju ni wọn kọkọ gbe jade ninu iwe imọ ijinlẹ ori ayelujara, Science Direct, ninu oṣu Kinni.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn dokita nigba ti ayẹwo imọ ẹrọ fihan pe ife imomi oni gilaasi lo wa ninu ile itọ rẹ.

Arabinrin naa to wa lati Tunisia, jẹwọ pe oun lo ife naa ni ọdun diẹ sẹyin fun adun ibalopọ.

Awọn obinrin gbagbọ pe tawọn ba ki nnkan soju ara, yoo fun wọn ni adun ibalopọ:

Niṣe lo ki ife naa si iho ti itọ n gba jade dipo oju ara ti obinrin n gba ni ibalopọ.

Iṣẹ abẹ si ni awọn dokita fi gbe gilaasi naa jade, lẹyin ti wọn fọ okuta ile itọ to yii ka.

Iyalẹnu to wa ninu ọrọ arabinrin yii ni pe ko si nkankan to ṣe ife naa lati ọdun to ti wa ninu ara rẹ. Ko pawọ da, bẹẹ ni ko fọ.

Ninu imọ ijinlẹ, 'urethral sounding' ni wọn n pe nkan ti obinrin naa sẹ.

Awọn to ma n sẹ nkan yii ma n ki oriṣiriṣi nkan bi ife omi oni gilaasi sinu ibi ti itọ n gba jade lati mu ki adun ibalopọ pọ si fun wọn.

Igbagbọ wọn ni pe ti nkan ba wa ninu ile itọ, yoo fun wọn ni adun to pọ lasiko ti wọn ba n ni ibalopọ.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Nkan to yẹ ki o mọ nipa 'Urethral Sounding':

Oju opo akọsilẹ nipa eto ilera, Wed MD, sọ pe awọn onimọ isẹgun oyinbo ma n lo ilana yii lati fi ṣi ile itọ, lasiko ti wọn ba fẹ ẹ yọ ohunkohun to há sibẹ.

Ṣugbọn, awọn irinṣẹ ilera ni wọn ma n lo, kii ṣe awọn nkan to le pani lara.

Iwadii sọ pe tọkunrin-tobinrin lo ma n ṣe e, ti wọn si ma n lo awọn nkan bi ikọwe (pencil), waya, awọn eso to jọ nkan ọmọkunrin, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ewu to wa ninu ṣiṣe 'urethral sounding'

Ọgbẹ

O ṣeeṣe ki o ma le yọ nkan naa mọ fun ra rẹ

O le lu iho sinu ile itọ rẹ tabi ko o ma le tọ rara

Kokoro aifojuri ninu ile itọ (UTI)

Itọ yoo ma rin jade si ara rẹ

O le ba kindinrin jẹ

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun