Sexual Abstinence: Ṣé lóòtọ́ ni àìní ìbálòpọ̀ lfún ìgbà pípẹ́ yóò sẹ àkóbá fún ara rẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lootọ ni ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin jẹ nkan to ni adun pupọ, to si ma n mu ara ya daada, ṣugbọn bo sẹ dun to, awọn kan pinnu lati mu ara duro fun asiko kan.
Imọ ijinlẹ sayẹnsi fihan pe ọpọlọpọ anfaani lo wa ninu ibalopọ loore-koore fun awọn ololufẹ.
Igbagbọ awọn eeyan kan ni pe o lewu fun ẹni ti ko ba ni ibalopọ fun ọjọ pipẹ, to si le koba ilera ara wọn. Ṣugbọn ṣe lootọ ni?
Iwadii kan ti BBC Igbo ṣe nipa ifọrọwanilẹnuwo pẹlu dokita onimọ iṣegun oyinbo kan, Udodi Okoli dahun ibeere yii.
Dokita Okoli sọ pe imọ sayẹnsi ko tii sọ boya ewu kankan wa fun ilera ẹnikẹni ti ko ba ni ibalopọ .
O ni nkan ṣoṣo ti sayẹnsi sọ ni pe o le nipa lori ironu iru ẹni bẹ́ẹ̀, paapaa nitori bi awọn eeyan ṣe le ma a fi ẹni naa ṣe yẹyẹ.
Lara anfaani ibalopọ gẹgẹ bi dokita ṣe sọ ni pe, o ma n mu ki ara eeyan sinmi lẹyin wahala.
- Ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń wo ìhòhò obìnrin dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta
- Iye ọmọ tí ẹ bá lè tọ́ ni kí ẹ bí- NAPTIP
- Obìnrin kan dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn wíwẹ ọmọ rẹ̀ lómi gbígbóná nítorí kọ́kọ́rọ́
- Njẹ́ o mọ nípa ògẹ̀dẹ̀ tuntun tó lè bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lágbàyé?
- Ìyàwó Ẹlẹ́ṣìn ìlú Wukari yarí pé láyé òun ò lè gbà kí ọkọ́ òun wọ igbó mọ́ fún ìsìnkú Ọba
- Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
Dokita miran, Malik Haruna King sọ pe ko si nkan to buru ninu ki eeyan pinnu pe oun ko fẹ ni ibalopọ. Iru ẹni naa ko le ni wahala kankan ni agọ ara rẹ.
"Koda, obinrin tabi ọkunrin ti ko ba ni ibalopọ fun igba pipẹ, yoo gbe igbeaye to dara bi awọn to n ni ibalopọ.
Ṣe aini ibalopọ loore-koore le fa jẹjẹrẹ koropọn fun ọkunrin?

Oríṣun àwòrán, malayalamemagazine.com
Dokita Okoli sọ pe irọ patapata ni bi awọn kan sẹ ma n sọ pe ọkunrin ti kii ba ni ibalopọ rara tabi ni igba gbogbo yoo ni jẹjẹrẹ ni koropọn rẹ,
Okoli sọ pe yatọ si ibalopọ pẹlu obinrin, awọn ọkunrin ma n da atọ loju orun, eyi ti awọn oni Gẹẹsi n pe ni 'Wet Dream'.
Fun obinrin, ọ̀kan lara kudiẹ-kudiẹ to wa ninu aini ibalopọ fun igba pipẹ ni pe o le fa irora nigba to ba fẹ ẹ ni.















