Ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń wo ìhòhò obìnrin dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta

Ẹni to n yọju wo nkan

Oríṣun àwòrán, Screenshot of sihlohete

Ọga ọlọpaa Met kan to n eo ihoho awọn obinrin niluu London ti ri ẹwọn ọdun mẹta he lọjọ Ẹti.

Ọlọpaa ọhun, Neil Corbel, to jẹ ọmọ ogoji ọdun ni ọwọ tẹ nibi ti o ti n fi kamẹra ya fidio awọn obinrin to wa ni ihoho ọmọluabi.

Corbel sọ fun ileẹṣọ ọlọpaa wi pe wiwo ihoho papaa julọ awọn ti wọn ba n ba ara wọn lopọ ti mọ oun lara.

Obinrin mọkalelaadọta ni wọn ri pe Corbel ti ya fidio wọn eyi ti mọkandinlogun ninu wọn jẹri tako o.

Corbel to jẹ ọlọpaa to maa n gbogun ti awọn agbesunmọmi tẹlẹ maa n lo oriṣiiriṣii ọgbọn lati tan awọn arinrin-oge ki o le ya fọto fun wọn.

Lati ibẹ ni yoo ti yoo ti gbe kamẹra sinu yara ile itura tawọn obinrin naa ba wa lati le ya ihoho wọn.

Corbel to ti bi ọmọ meji ni a gbọ pe o maa n fi kamẹra pamọ sinu kọkọrọ, gilaasi, ṣaja foonu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Arinrin-oge kan to gba lati ya fọto ni ihoho lo ṣe akiyesi pe Corbel n ya fidio ihoho pamọ.

Adajọ Martin Edmunds dajọ ẹwọn ọdun mẹta fun gbogbo ẹsun ti wọn ka si Corbel lọrun eleyii to waye ni London, Manchester ati Brighton laarin oṣu kinni ọdun 2017 si oṣu keji 2020.