Buhari: Ààrẹ ṣàlàyé bí yóò ṣe fi Nàìjíríà sílẹ̀ ju bó ṣe bá a lọ

Ààrẹ Mohammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ijọba oun ti ni ipinu lati gbe ijọba Naijiria le ẹni to ba n bọ lọwọ ju eyi ti wọn jogun lọ nigba ti wọn de ijọba.

O wa rọ awọn eeyan lati ṣe dẹẹ̀ẹ́dẹ̀ẹ́ ninu ṣiṣe agbeyẹwo akitiyan ohun ti ijọba rẹ ti ṣe titi di asiko yii.

Buhari tilẹ sọ ni pato pe ki wọn ṣe agbeyẹwo awọn ipinu ti oun ṣe nigba to n polongo idibo lọ dun 2015.

O sọ ọrọ yii lasiko ibẹwo rẹ si ilu Kaduna to lọ fun ibẹwo ọlọjọ meji lati ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe ni Kafanchan, Kaduna ati Zaria.

l'Aafin Emir ilu Jema'a, Alhaji Muhammadu Isa Keji ni Kafancahan ni Aarẹ Buhari ti ni oun yoo wa nkan ṣe si ọrọ oṣelu ti yoo mu ayipada ba igbe aye awọn eniyan.

O ni awọn yoo lo ọlọpaa ati sọja lasiko idibo lati koju ipenija aabo amọ ki awọn araalu ni igboya ninu ijọba lati ṣe eto idibo ti ko ni ni kọnu n kọhọ kankan ninu.

Àkọlé fídíò, Kaun

"Ki ẹnikẹni ma ṣe gba ki wọn ko awọn janduku jọ lati mu awọn eeyan ni tipatipa. "Ẹ jẹ ki eyi ye daadaa", aarẹ ṣe ikilọ yii pẹlu atẹnumọ.

Ṣaaju ni Gomina Nasir El-Rufai mọ riri iṣẹ ti Aarẹ ṣe ni ẹka abo to si sọ ni paapaa agbekalẹ awọ ikọ alaabo kaakiri eyi to ni o mu adinku ba ikọlu si awọn eniyan.