Abuja rice pyramid fact check: Ẹ̀ka àṣewádìí BBC ti tú isu dé ìsàlẹ̀ kòkò ìrẹsì gogoro tí Ààrẹ Buhari ṣe ìfilọlẹ̀ rẹ̀

Fídíò kan tó tan ká orí ayélujára eyi to safihan bí wọn ṣe to ọpọlọpọ apo irẹsi lórí ara wọn pẹlu pako kii ṣe tí ibi tí Ààrẹ Buhari ti ṣe ifilọle irẹsi gogoro lọjọ Iṣẹgun ni Abuja.
Aworan apo irẹsi ti wọn to sori pako jẹ eto kan to waye ni ipinlẹ Ogun ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria.
Aworan naa jade lori iwe iroyin Nairaland ninu oṣu Kinni ọdun 2018 o si ti tan kaakiri ni gbogbo ọdun naa.

Oríṣun àwòrán, NAiraland
Amọṣa iwadii fihan latọwọ ẹka aṣewadii BBC ni Naijiria ti wọn lo aapu kan ti wọn fi n ṣewadii asiko ti wọn ya aworan pe aworan naa to ṣẹṣ tun tan ka ori ayelujara bi wọn to irẹsi gogoro sori pako wa lati ibi eto ti ijọba ipinlẹ Ogun ṣe.
Awọn eeyan kan lo pin aworan naa sori ayelujara paapaa loju opo Facebook ati WhatsApp lati ṣe keeta eto irẹsi gogoro ti ijọba apapọ ṣe ifilọlẹ rẹ eyi to wa lati awọ́n agbẹ to janfani akanṣe eto Banki apapọ Naijiria, "Anchor Borrower Programme".
Awọn eeyan lori ayelujara n pin aworan naa lati fesi si fidio eto tuntun ti aarẹ Buhari ṣe yii ti amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori iroyin, Lauretta Onochie fi sita.
"Lauretta Onochie, too ba pin fidio ir tan lori irẹ́si gogoro tan koo gbe Buhari l ibi ti awọn irẹsi naa wa kẹ jọ lọ ra a. Ohun ti wọn kọ sori fọto ti wọn n gbe ka.

Iwadii tootọ
Ootọ ọrọ to wa nibẹ ni pe awọn irẹsi gogoro ti wọn to jọ lori ara wọn ni ẹka katakara ilu Abuja ko ni itẹlẹ pako kankan - wọn kanlẹ to awọn apo irẹsi sori ọra ni, eyi yat si nkan tawọn eeyan n ri ninu fọto ti wọn n pin kiri ori ayelujara.
Bakan naa, awọn baagi ti wọn fi ko irẹsi nilu Abuja yatọ si baag eyi to wa ninu fọto atijọ ọhun.
Ati pe aworan irẹsi gogoro ti ipinlẹ Ogun ṣafihan, gogoro tirẹ tun wẹ lẹgbẹ gogoro eyi ti Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ rẹ ni Abuja.

Lauretta tun ti lo awọn fọto tuntun ati fidio bi wọn ṣe ko awọn irẹsi naa jọ. Awọn aworan ọhun ko si ṣafihan pako kankan labẹ awọn irẹsi.
- Wo ìlú tí wọ́n ti ń gbé òkú ọba wọn pọ̀n lórí ẹṣin lọ fún ìsìnkú nínú igbó
- Pásítọ̀ ti ríran sí mi pé mà á jẹ Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2018- Dele Momodu
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí ayélujára sọ di ìlúmọ̀ọ́ká
- Muhammed Alfa gún ìyàwó rẹ̀ ọlọ́mọ mẹ́jọ pa nítorí pé ó ń ti ilẹ̀kùn mọ́rí
- 'Ìwọ tóo bá ní Sabuké ìwé mẹ́wàá, kò yẹ kóò súnmọ́ dídu ipò òṣèlú kankan'
Iwadii ni ibi eto naa fihan pe irẹsi gangan lo wa ninu awọn apo ọhun kii sii i ṣe polofo tabi iyẹpẹ gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ lori ayelujara.
Alaga ẹgbẹ awọn agbẹ onirẹsi, Aminu Goronyo sọ fun BBC pe o gba awọn ni oṣu mẹta lati to irẹsi gogoro naa.
Ijọba apapọ ni irẹsi gogoro ti awọn ṣide rẹ yii ni eyi to tobi ju ni Naijiria wọn si ni iye irẹsi ti awọn ti pese ni Naijiria ti fẹẹ to ilọpo meji lati igba ti Buhari ti gori oye ldun 2015.














