Gbajabiamila: Wo tuntun tí Gbajabiamila fẹ́ kí ilé aṣojúṣòfin dáwọ́lé lórí ẹni tó bá fẹ́ du ipò òṣèlú

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Gbaja.com

Adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ni awọn ti ṣetan lati ṣe atunṣe iwe ofin fun eto idibo abẹnu awọn ẹgbẹ oṣelu.

O sọ eyi ninu ọrọ ikini kuabọ rẹ si awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin nibi to ti ni ẹda iwe abadofin to n lọ kaakiri kii ṣe ọkan naa pẹlu eyi ti awọn fi ṣọwọ si Aarẹ Muhammadu Buhari torinaa oun yan igbimọ kan lati ṣe iwadii kikun lori rẹ.

Ninu iroyin miran lati ile aṣoju-ṣofin, Gbajabiamila pe fun ki wọn gbe ipele iwe to yẹ ki awọn to n gbero ati dupo aarẹ Naijiria atawọn ipo nla nla mii lọjọ waju soke ju bo ṣe wa lọ.

Àkọlé fídíò, Eba

Gbajabiamila lo sọ eyi lọjọ Aje nigba to n ba awọn akẹkọjade sọrọ ni ile ẹkọ giga fasiti ilu Eko.

O ni eyi ṣe pataki lati lee figagbaga pẹlu awọn igbesẹ kọọkan ni ọọrundunrun yii.

Gbajabiamila ni niwọn igba to jẹ pe iye ọjọ ori awọn to lẹtọ lati du awọn ipo nla nla naa ti dinku bayii, o ṣe pataki lati jẹ ki iye ẹkọ to yẹ ki wọn ka naa sun soke.

O ni yoo jẹ igbesẹ mii lati ṣe ayipada ilana eto idibo ati pipese adari gidi fun orilẹede.

O ni "bakan naa mo tun gbagbọ pe o yẹ ki ile igbimọ aṣofin boju wo abala 131(D) ninu iwe ofin ọdun 1999 pẹlu ero ati sun iye iwe to yẹ ki awọn to ba fẹ du ipo aarẹ Naijiria lọjọ iwaju atawọn ipo nla nla mii soke koda to fi mọ fun ile igbimọ aṣofin gan lodi si ipele iwe mẹwa tabi eyi to jọ ọ ti wọn n lo lọwọlọwọ yii.

Bakan naa lo mẹnu baa pe ki awọn ile ẹkọ giga mu agbega ba kikọ iṣẹ ọwọ ninu gbogbo imọ ẹkọ wọn tori pe "ni bi aye ṣe n yi lọ yii, awọn owo ti yoo gbilẹ yoo pọ ju iṣẹ ijọba ti eeyan lee ri lọ. O yẹ ẹka eto ẹkọ wa ṣe eto lati gbaradi fun awọn araalu lati di oniṣẹ ọwọ aladani ju ẹni to n wa iṣẹ kiri lọ'.