Sen. Ojudu on Tinubu: Ìdí rèé tí mí o fí ní ṣàtilẹ̀yin èròngbà Tinubu là tí di ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ṣaaju idibo aarẹ ọdun 2023, olùrànlọwọ aarẹ Buhari lori ọrọ oṣelu Seneto Babafemi Ojudu ti jade lati sọ pe oun ko ṣetán lati gbaruku ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria.
Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Isẹgun, o ni ko soun to jọ ninu ọrọ tó gbòde pe ẹnikẹni tó bá sunmọ Tinubu ti ko si gbe lẹyìn rẹ jẹ ọdàlẹ.
Ojodu ni ifẹ Tinubu si rinlẹ lọkan oun paapa ipa to ko lati satlẹyin fún òun lasiko ìjọba ologun.
Lọsẹ to kọja yi ni Tinubu kéde erongba rẹ lati dije ipò ààrẹ Naijiria.
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá mẹ́fà tí ẹnu ń kùn lórí ìbò ààrẹ ọdún 2023
- Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- Ìdìbò 2023: Àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu yóò kojú nínú ìrìnàjò rẹ̀ nìyí
- Tinubu hùwà ọdàlẹ̀, Ọlọ́run kó sì ní gbà fún un lórí èròngbà rẹ̀ - Ohanaeze Ndigbo
- Ǹjẹ́ obìnrin leè di "virgin" padà bí kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbá pípẹ́? - Onímọ̀ nípa ìbálòpọ̀ bá BBC sọ̀rọ̀
Lẹyìn ikede yi la bẹrẹ sí ní ri awọn to láwọn yoo pẹlu rẹ ati awọn to ni awọn yoo tako.
Ninu awọn alatako yi awọn tó sunmọ Tinubu naa wa ninu wọn.
Babafemi Ojudu sọ ninu atẹjade rẹ pe oun ri tàwọn kan lọ wù apilẹkọ toun kọ nigba ọjọ ibi ọgọta ọdún Tinubu
"lootọ mo kọ nkan to wa nínú rẹ ti ọpọ iru rẹ mi yóò sì waye nigba ti mo ba kọ ìwé ìtàn igbesiaye mi"
"Ọjọ ti pẹ tí ojo ti n pa igun èmi àti Tinubu bọ.Ẹ ma tori ìyẹn wa fi sọ pe ọdàlẹ ni mi ti mi o ba gbaruku ti lati di aarẹ"
O tẹsiwaju pe "Asiwaju mi sí ni Tinubu jẹ ti mo sí mọ riri ipa to ko fún mi nípa atilẹyin lasiko ìjọba ologun."
"Àmọ́ Tinubu mọ pe mi kii ba ero máa wọ tẹle èèyàn lẹyìn. Arojinlẹ máa n tẹle igbesẹ ti máa bá gbé.Oun gaan mọ pe eeyan ko le mu mi lati se nkan ti mi o ba fẹ ṣe".
- Ẹ yìnbọn pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n- Mínístà Aregbesola
- Pẹ̀lú bí Dayo Kujore ṣe fi ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà tó, kò sí ẹnìkan tó bá wa kẹ́dùn lẹ́yìn ikú rẹ̀- AyinkeKujore
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ọ̀rọ̀ Kanu lẹ́yìn tó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Gbajabiamila pé: Kò yẹ kí ẹni tí kò kà ju WAEC bíi Buhari jẹ Ààrẹ Naijiria mọ́
- Ilé ẹjọ́ ní kí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò san 4.5m fún alájọgbélé wọ́n tí ariwo 'toilet' wọn kò jẹ́ kó rí oorun sùn
O sakawe awọn iṣẹlẹ orisirisi to fi mọ bóun kó se torí pé Gani Fawehinmi ati Abiola se oun lóore ki oun wa tori rẹ ma tẹle nkan to tọ ati eyi ti ọkan oun yan.
Lakotan Ojudu salaye pe oun fẹ daada fún Tinubu amọ eri ọkan ko ni jẹ ki oun gbe lẹyìn rẹ tabi dibo fún lasiko idibo abẹnu ẹgbẹ ApC to n bọ.
"Ẹtọ mi ni. Mo ti kọja ọgọta ọdún.Mo fẹ ẹ padanu ẹmi mi nítorí ẹtọ lati yan eni to bá wù mí lọkàn yi.Koda wọn torí rẹ fi mí sí atímọlè ati ijiya mii ti mo kojú."
O pari ọrọ rẹ pe ọtọ ní Ọlọrun Tinubu ọtọ sí ni toun.


















