Dayo Kujore: Ọmọ olóògbé olórin Juju fi àidunnú rẹ̀ lẹ́yìn tó ní àwọn èèyàn kò kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí rẹ̀

Aworan Dayo Kujore

Oríṣun àwòrán, Dayo Kujore

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọtitọ ni ọrọ tawọn Yoruba maa n sọ pe ọjọ ti a ba ku laa dere, eniyan o sunwọn laaye.

Ayinke Dayo Kujore to jẹ ọmọbinrin gbajugbaja olorin Juju to di oloogbe, Dayo Kujore lo pariwo sita pe awọn ọmọ Naijiria ko nan an ni rara lati ba ẹbi oloogbe kẹdun.

Ayinke fi ẹdun ọkan rẹ han loju opo Facebook rẹ nibi ti sọ pe awọn kii mọ iyi eeyan to jẹ ti wọn.

''O ṣeni laanu, o si buru jai bi awọn ọmọ Naijiria kii tii ka ohun to ba jẹ ti wọn kun.

Lẹyin ti Dayo Kujore lo gbogbo ọjọ rẹ lati sin orilẹede Naijiria ati ipinlẹ rẹ, Ogun, ko si ẹni to wẹyin lati ba ẹbi rẹ kẹdun.

Dayo Kujore lo ẹbun orin ti Eledua fi jinki rẹ lati ṣe igbelarugẹ aṣa orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni o lo ẹbun rẹ lati so Naijiria pọ, ṣugbọn lẹyin ti o ti ku tan, ko si ẹnikan to kọwe ranṣẹ tabi wa lati bawa kẹdun.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Eleyii buru jai! Ma a sun laya Olugbala baba mi, Wonder Dayo Kujore.

Àkọlé fídíò, Eba

Ti eeyan ba maa n tun aye wa, mo ṣi maa tun jẹ ọmọbinrin rẹ.

Iku baba mi bami lojiji, mi o tiẹ lero rẹ rara, baba mi ọwọ, Idowu Adedayo Kujore, sun re o,'' Ayinke Dayo Kujore lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Dayo Kujore gbajugbaja olorin Juju ni Naijiria ti dagbere faye lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Dayo Kujore ti ọpọ si mọ nitori ẹbun ti Eledua fun nipa arokọ ati agbekalẹ orin.

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

Oludasilẹ orin Sọkọ, Kujore kọṣẹ orin labẹ Prince Adekunle to si n ta gita ninu awọn orin manigbagbe ti Adekunle kọ bi "Aditu ede" ati "Eda n reti eleya".