Dele Momodu: Mo ni gbogbo àmúyẹ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní 2023

Oríṣun àwòrán, @Dele Momodu
Gbajúgbajà akọròyìn tó ti fi èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 2023, Dele Momodu ti ní láti ọdún 2018 ni ẹnìkan ti fi àtẹ̀jíṣẹ́ ráńṣẹ́ sí òun wí pé òun yóò di Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ká sí nígbà náà, àsìkò ti tó báyìí kí àlá onítọ̀hún wá sí ìmúṣẹ.
- Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- ''A kò ní dẹ́kun ìfẹ̀hònúhàn àyàfi tí ìjọba àtàwọn aláṣẹ FUTA bá gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò àwa akẹ́kọ̀ọ́''
- Èmi ò sọ̀rọ̀ sí Bobrisky lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní Benin, irọ́ ni ìwé ìròyìn tó gbé e pa mọ́ mi- Femi Branch
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí ayélujára sọ di ìlúmọ̀ọ́ká
- Àlàyé rèé lórí bí àwọn agbébọn ṣe pa ṣọ́jà méjì, ọlọ́pàá àtọ̀pọ̀ olùgbé ìletò kan ní Kebbi
Dele Momodu sọ èyí ní orí ẹ̀rọ ayélujára Facebook ní òwúrọ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀.
Ó ní òun ní gbogbo ohun tó yẹ láti lè fi tu kọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà à ti pé òun Ọlọ́hun mọ̀ ọ́ mọ̀ pa òun mọ́ di àsìkò yìí.

Oríṣun àwòrán, @Dele Momodu
"Ẹni tí Nàìjíríà nílò lásìkò yìí ni ẹni tuntun tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìbàjẹ́ àtẹ̀yìn wá".
"Mo ti ṣet'sn láti lo gbogbo ẹ̀bùn tí Ọlọ́hun fún mi láti fi sin Nàìjíríà".
Bákan náà ló fi kun un pé òun tí ń kó ipa ribiribi fún àwọn ènìyàn káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípa ṣíṣe àgbékalẹ̀ ìkúnpá owó.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti ṣe ìforúkọsílẹ̀ fún ètò ìkúnpá owó náà lórí áàpù tì àwọn ṣàgbékalẹ̀ látọwọ́ obìnrin ará ilẹ̀ Ghana kan.

Oríṣun àwòrán, @Dele Momodu
Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rẹ̀rìndínlógójì orílẹ̀ èdè yìí ni àwọn ènìyàn ti ṣe ìforúkọsílẹ̀ tí àwọn sì ti ń ṣe ohun tí ipá àwọn ká fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́.
- Dandan ni kí agbára ìṣèjọba padà sí Gúsù Naijiria ní 2023 - Àwọn olórí ẹ̀yà ní Gusu
- Àwọn àwòrán tó ta lẹ́nu nìyí látibi ayẹyẹ ọdún 51 Alafin Oyo lórí àpèrè
- Lórí ìdigunjalè sí Kemi Afolabi, ohun tí òṣèrè náà sọ fáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ rèé
- Kí ni Saheed Balogun àti Shina Peters wá lọ sí ilé Ààrẹ Buhari l'Àbuja?
- Nàìjíríà ló dáńtọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2021 ní Cameroon- Asamoah Gyan













