FUTA protest: 'A kò ní dẹ́kun ìfẹ̀hònúhàn àyàfi tí ìjọba àtàwọn aláṣẹ FUTA bá gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò àwa akẹ́kọ̀ọ́''

Oríṣun àwòrán, FUTA
Ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ to wa niluu Akure, FUTA ti fi aake kọri pe awọn ko ni dẹkun ifẹhonuhan lori eto abo to mẹhẹ layika ile ẹkọ naa.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa, SUG fi sita lọjọ Aje ni wọn ti ṣalaye pe ayafi ti ijọba ati awọn alaṣẹ ile ẹkọ ba gbe igbesẹ lori ileri ti wọn ṣe lori ọrọ naa loku.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ SUG naa, Kọmureedi Ibiyemi Abiodun ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa ko le la oju silẹ ki awọn akẹkọọ ṣi maa jiya.
- Èmi ò sọ̀rọ̀ sí Bobrisky lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní Benin, irọ́ ni ìwé ìròyìn tó gbé e pa mọ́ mi- Femi Branch
- Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí ayélujára sọ di ìlúmọ̀ọ́ká
- Láìṣẹ̀, láìrò, Arákùnrin ẹni ọdún 43 fi ipá ba ìyá arúgbó ẹni ọdún 80 lo pọ
- Gómìnà Wike dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín ọlọ́pàá, Sífú dìfẹǹsì lórí ẹsùn fàyàwọ́ epo rọ̀bì
- Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Àlùbọ́sà Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ
Kọmureedi Abiodun fikun ọrọ rẹ pe igbayegbadun ati ati abo awọn akẹkọọ FUTA lo jẹ ẹgbẹ SUG logun.
Ọgbẹni Abiodun fikun ọrọ rẹ pe iwọde naa si n lọ lọwọ lasiko ti SUG fi atẹjade yii sita.
Ati pe igbẹkọ ati gbogbo eto ti wa ni idaduro bayii.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ rọ awọn akẹgbẹ rẹ ti ko tii darapọ ifẹhonuhan ọhun lati darapọ ni kiakia nitori ohun to ba ti ba oju ti ba imu naa.
O ni gbogbo iwa ti ko bojumu to n lọ layika ile ẹkọ naa gbọdọ wa si opin.














