Nasarawa Rape: Ọwó ọlọ́pàá Nasarawa tẹ arákùnrin ẹni ọdún 43 tó fipá bá ìyá arúgbó lo pọ

Ifipabanilopo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láìṣẹ̀, láìrò, Arákùnrin ẹni ọdún 43 fi'pa ba ìyá arúgbó ẹni ọdún 80 lo pọ

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Nasarawa ti mu arakunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan lori ẹsun pe o fipa ba iya arugbo kan lajọsepọ.

Eni ọgọrin ọdun ni iya arugbo yi.

Atẹjade lati ọdọ alukoro ọlọpaa Ramhan Nansel lọjọ Aiku ni Lafia olu ilu Nasarawa lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Gẹgẹ bo ti se wi, lọjọ Kẹrinla, osu kini ni wọn mu ẹjọ yi wa si agọ ọlọpaa Garaku.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Dan'asabe Eddo, to jẹ ọmọ bibi Kaduna ni afurasi taa n wi yi to si n gbe labule Garaku nijọba ibilẹ Lokongo.

"Wọn fẹsun kan an pe o fipa wọ ile arugbo ẹni ọdun ọgọrin to n da gbe ile yi to si fipa ba lajọsepọ''

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Atẹjade naa tẹsiwaju pe "Kete ti a gbọ nipa isẹlẹ yi lawọn ọlọpaa agọ to wa ni Garaku gberasọ ti wọn si mu afurasi yi''

Alukoro ọlọpaa naa ni Kọmisọnna ọlọpaa Adesina Soyemi, ti pasẹ pe ki ẹka ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Lafia bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian