Uses of Garlic: Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ

Galiiki

Oríṣun àwòrán, Others

Ilumọọka nkan isebẹ ti o loorun aladun ni Garlic tabi aayu jẹ.

O kun fun eronja taa n pe ni Sulphur eyi to mu ki o maa se ara loore pupọ

Orisirisi ni anfaani to wa lara aayu ninu wọn la si ti ri pe o maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu eeyan.

Awọn onimọ sọ pe aayu a maa se anfaani fun ọkan nitori kii jẹ ki oju isan ti ẹjẹ maa n gba di.

Koda a gbọ pe ti eeyan ba mu aayu pẹlu miliki, a maa fun ni lokun paapa lati le fi se bi ọkunrin pẹlu obinrin rẹ.

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Die ree lara awọn oore to wa fun ara wa ti ba n lo aayu:

Kikoju awọn kokoro aifojuri

Aayu wa lara nkan tawọn to mọ nipa tewetegbo a maa lo lati fi koju aisan orisirisi.

Bi o ba jẹ ti ka koju ikọ tabi ọfikin,aayu da pupọ.

Lilo aayu a maa jẹ ki ikun jade daada ninu imu eeyan.Bẹẹ la tun gbọ pe o da fun egungun ara wa.

Aayu a maa jẹ ki ọpọlọ ji pepe

Bi eeyan ko ba ki n ranti nkan daada,a gbọ pe aayu ma n sọ ọpọlọ eeyan ji pepe pada.

Kii jẹ ki awọn cell inu ọpọlọ ku ti a si tun maa fun eeyan lokun ati agbara paapa ti ẹni naa ba n se ere idaraya.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Afẹfẹ oxygen to ba yẹ ko maa gba inu isan kọja daada, aayu maa n se iranwọ fun.

Bi eeyan ba tu fẹran ko maa mu omi aayu saaju ki o to fi nkankan sinu laarọ eleyi a maa jẹ ki onitọun din sisanra ku.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Awọn nkan wọnyi ni diẹ lara anfaani ti o wa lara aayu.

Lori awọ ara wa, o se anfaani to pọ

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Awọn orisi aisan to maa n koju awọ ara eeyan naa a maa ri itọju ti onitọun ba lo aayu.

Bo jẹ kokoro aifojuri bakiteria ni tabi fungal, aayu ni awọn eronja kan to le ba eeyan koju awọn kokoro aifojuri wọn yi.

Ororo aayu sisẹ daada bi eeyan ba fẹ tọju lapalapa eela tabi awọn kokoro ara miran.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Fawọn obinrin to fẹ ki irun wọn gun daada naa, wọn le lo aayu ti wọn peelo rẹ pẹlu oyin.

Eleyi a maa mu ki irun gun daada tikii si jẹ ki irun maa ja.

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

Lasiko yi o tọ ki a fi to ara wa leti pe bi eeyan ba jẹ aayu ni tutu, o maa n mu ki ẹnu eeyan maa bu ti.

Nitori naa, arọwa si yin ni pe ki ẹ maa fọ ẹnu yin lẹyin ti ẹ ba jẹ aayu.