COVID-19: Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun lórí COVID-19, Ó mú àdínkù bá ìye èèyàn tó lè wọ ṣọ́ọ̀ṣì, mọ́sáláṣí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria, ti kede pe ki awn ileejọsin gbogbo rii daju pe awọn ko gba ju eeyan ida aadọta iye awọn to ye ko wọ ileejọsin wọn nitori ajakalẹ̀ aarun COVID-19.
Akọwe ijọba apapọ Naijiria to tun jẹ alaga igbimọ tẹẹkoto lori ajakalẹ aarun COVID-19, Boss Mustapha lo ṣe ikede naa ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ.
Ijọba Naijiria rọ awọn ẹbi kọọkan lati rii daju pe wọn fi gbedeke le iye awọn eeyan to lee wa bẹ wọn wo nile lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii ki Naijiria maa baa tun bọ si saa ọwọja kẹrin ajakalẹ arun naa lẹyin ọdun.
- Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Ta ni Ashley Folasade Adegoke ti ayé ń pariwo pé òun ni Olorì tó máa rọ́pò Naomi Silekunola?
- Kò tíì pẹ́ jù bí ìjọba bá leè sọ ẹni tó pa olóògbé Bola Ige- Gani Adams
Awọn ilana tuntun yii n jade lasiko ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC n ke tantan pe alekun onida ẹẹdẹgbẹta ninu ọgọrun (500%) ọṣẹ ajakalẹ aarun COVID-19 ati iye awọn to n lugbadi rẹ.
Igbimọ tẹẹkoto ti aarẹ gbe kalẹ naa ni orilẹede Naijiria ti ko wọ inu ọwọ kẹrin ọwọja kokoro arun COVID-19 nitori oniruuru awọn eeyan tuntun to n lugbadi aarun naa.
Awọn ilana a n tẹẹle tuntun ti ijọba gbe kalẹ fawọn ọmọ Naijiria.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita naa, alaga igbimọ tẹẹkoto ti aarẹ gbe kalẹ naa ṣalaye pe:
- Ilaji iye awọn eeyan ti ijọ kọọkan ba gba ni ki wọn pese aaye fun (50%)
- Ipejọpọ yoowu to ba ju eeyan aadọta lọ, ita gbangba ni yoo ti maa waye nitori ati lee tẹle ilana itakete sira ẹni.
- Ijọba Naijiria rọ awọn ẹbi kọọkan lati rii daju pe wọn fi gbedeke le iye awọn eeyan to lee wa bẹ wọn wo nile lasiko pọpọṣinṣin ọdun.
- Ki awọn eeyan o yago fun irinajo lati ipinlẹ si ipinlẹ ti ko ba pọn dandan.
- Kiawọn eeyan o maa wọ ibomu ki wọn si maa lo ọṣẹ apapkokoro sanitaisa, (Sanitizer)
- Ẹ ṣe ayẹwo COVID-19 bi ẹ ba fẹ rinrinajo.
- Rii daju pe o ti gba ẹkunrẹrẹ abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ati agbakun abẹrẹ ajẹsara naa ti wọn n pe ni Booster dose fun awọn to ba ti too gba.













