NIMC server hacked?: Ajọ NIMC fèsì sí ìròyìn tó ní àwọn olè orí ayélujára kọlu ìtàkùn wọn

Oríṣun àwòrán, NIMC
Ajọ to n moju to kaadi idanimọ lorilẹ ede yi taa mọ si NIMC ti ṣalaye pe ko si akọlu kankan si awọn ẹrọ ayelujara ti wọn n fi akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria si.Ọga agba ajọ naa, Onimọẹrọ Aliyu Aziz lo fi ọrọ yi lede lataari iroyin kan to jẹyo pe ajideta ori ayelujara kan ti ṣakolu si ẹrọ ayelujara wọn.Aziz ṣalaye pe ọpọlọpọ igbesẹ ni awọn ti gbe lati rii pe apamọ wọn lori ẹrọ ayelujara ni ko ri akọlu kankan.
- "A ò lè sọ pàtó ibi tí Raheem Adedoyin wà báyìí"; "Àmọ́ ẹ mọ̀ nígbà tí ọlọ́pàá kò tíì wá a"- Agbẹjọ́rò Adedoyin àti ti ìdílé Timothy takurọ̀sọ
- Afọbajẹ tí mò ń ṣe látọdún yìí ti tó, ẹ jẹ́ kí ẹ̀mi náà dádé Ààrẹ - Tinubu
- 'Ìdí nìyí tí mo fi yọ kórópọ̀n mi kí n má lè bá obìnrin kankan sùn'
- Ìgbà márùn ùn ọtọ́ọ̀tọ tí Nàìjíríà àti Egypt kojú lórí pápá ní Afcon
- Dayo Kujore: Àgbà olórin juju dágbére fáyé pé ó dìgbòóṣe!
- Wo bí ọ̀fìnkìn ṣe lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àrùn Covid-19
O fi kun ọrọ rẹ pe irufẹ abo to daju jakejado agbaye ni wọn fi n da bo apamọ naa gẹgẹ bii ajọ to n daabobo akọsilẹ to ṣe pataki ju lọ nilẹ Naijiria.Aziz fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ajọ naa yoo tubọ maa sa gbogbo ipa rẹ lati rii pe abo to munadoko wa lori akọsilẹ to wa ni ikawọ wọn.O gboriyin fun awọn ile-iṣẹ ijọba bii Ọlọpaa, ẹṣọ oju popo ati ajọ to n ri si idanwo aṣewọ ile ẹkọ giga, JAMB fun bi wọn ṣe ni igbẹkẹle ninu ilana ti awọn fi kalẹ lori lilo nọmba idanimọ orilẹ ede yii.Aziz tun parọwa fun gbogbo ọmọ Naijiria ati olugbe lati rii pe wọn forukọ silẹ fun nọmba idanimọ eyi to jẹ ojulowo ọna lati ṣafihan eeyan to jẹ olugbe ilẹ yii ni ilana ti ofin.











