Terhemen Anongo yọ kórópọ̀n rẹ̀ nítorí kí ara rẹ̀ má dìde láti lè bá obǹrin sùn

Terhemen Anongo

Oríṣun àwòrán, The PUNCH

Àkọlé àwòrán, Terhemen Anongo

Ọkùnrin kan, Terhemen Anongo, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì tí kò lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní ipele karùn-ún ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ìbàdàn ti yọ kórópọ̀n rẹ̀ kejì.

Ìwé ìròyìn The PUNCH tí kọkọ fi ìròyìn kan léde nínú oṣù kẹta ọdún 2021 nípa arákùnrin náà tó yọ kórópọ̀n rẹ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó di ẹni tó ń ti ọmọlanke látàrí àìlè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́.

Anongo ní nítorí òun kò nì ìyàwó pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òun nínú ẹ̀sìn àti ohun tí òun kà nípa Origen Adamantius tó jẹ́ adarí ẹ̀sìn nígbà kan rí ní Egypt ló fún òun ní ìwúrí láti tẹ ara rẹ̀ lọ́dà.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke

"Nígbà tí mo fẹ́ yọ kórópọ̀n àkọ́kọ́, ẹ̀jẹ̀ pọ̀ tó ya lára mi, èyí tó mú mi sá lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú".

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

"Ṣùgbọ́n nígbà tí mo fẹ́ yọ ẹlẹ́kejì, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ níbi ti àkọ́kọ́, mo ṣe é dada. Ẹnìkan ń wá bámi tọ́jú rẹ̀".

Àkọlé fídíò, Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Orí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

Ó ní ìgbàgbọ́ òun nínú ẹ̀sìn ni òun fi yọ ọ́ àti pé àláfíà ni òun wà.