Ondo Prison: Àwọn ológun padà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fi ìdùnnú hàn pé àwọn ọmọ ológun ti padà sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n nì ìpínlẹ̀ náà.
Ẹ ó rántí wí pé lọ́jọ́ Ẹtì ni Gómìnà Akeredolu ti ké gbàjarè wípé àwọn ológun ti kúrò ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ìpínlẹ̀ ọ̀hún léyìí tó léwu fún ààbò ẹ̀mí àti dúkìá.
Bákan náà ló ní ó le fa kí àwọn jàǹdùkú ó ṣe ikọlù sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yóò sì sá lọ.
Akeredolu nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ìròyìn rẹ̀, Richard Olatunde fi síta, yin ilé iṣẹ́ ológun lákin fún fífetí sí igbe aye awọn ará ìlú.
"Inú wa dùn láti ri pé àwọn ológun ti padà sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìdáàbò bò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wa, tí a kò ní fi ṣeré rárá."
"Kò yẹ kí ọgbà ẹ̀wọ̀n báyìí, tó jẹ́ ohun ìní ìjọba àpapọ̀ wà láì ní ààbò tó péye fún ìdí kankan. Àmọ́ ṣá pípadà àwọn ológun náà jẹ́ ìgbésẹ̀ tó dára."
Ó fi kun un pé àti ilé iṣẹ́ ológun àti ọgbà ẹ̀wọ̀n ló jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n sì gbọdọ̀ máa lájọṣepọ̀ tó dán mọ́rán.
Akeredolu ní àwọn yóò máa ṣe àtìlẹyìn tó yẹ fún wọn tí wọn ba nilo rẹ.
















